Alaaja Rukayat Gawat-Oyefeso ki i se olorin Islam tawon
eeyan yoo sese maa beere pe ta a lo n je bee, ki won too mo on, oodu lobinrin
naa laarin awon olorin egbe e ki i saimo foloko rara. Ohun too tun waa je ki
oro obinrin olopolo pipe yii yato sawon olorin egbe e yooku ni pe okan ninu
awon omo gbajugba sorosoro ori telifisan, Alaaji Rasak Aremu Gawat ni.
Opo rekoodu ni Rukayat tawon ore e maa n pe ni Aduke ti gbe
jade, bee lo ti gba ami-eye lopolopo. Yato siyen, okan Pataki ninu awon olorin
Islam ti imura re ko tako esin rara ni, e o le ri Rukayat ko san nnkan moju bawon
obinrin olorin yooku se maa n se. Bee ni obinrin tun je onisowo aso, bee lo tun
ni ileese ti won n se omi inu ora ati
inu ike.
Laipe yii Rukayat ba wa soro nipa igbesi-aye e, bo se di
olorin atawon nnkan mi-in nipa e. E ma a ba wa ka lo
OJUTOLE: E salaye fun wa nipa yin?
Alaaja Rukayat Gawat-Oyefeso: (Orin lo fi da wa lohun) ‘Eni
ti yoo peegan ajanaku ni yoo so pe oun ko mo erin, ko seni ti ko mo Aduke
Rukayat, riri ,e saa ti mo bo se n lo, logo mi niyen, imole yin naa ni’
OJUTOLE:
Bawo le se bere ise orin?
Alaaja
Rukayat Gawat: Nibo ni mo ti fee bere bayii, lati kekere nileewe alakobere ni
mo ti bere, a si tun se e wo ileewe girama, nigba ti mo jade nileewe giga
yunifasiti ni mo mu un ni koko. Ti a ba ni ka maa ka odun, o ti le ni ogun
daadaa ti a ti wa lenu ise yii,a si dupe lowo Olorun pe a ko si leyin ninu awon
olorin lorile-ede yii.
OJUTOLE:
Ki lawon obi yin so nigba ti e koko bere ise orin?
Alaaja
Rukayat Gawat: Won ko gba o, baba mi yari kanle pe awon ko fe ki n korin, ohun ti won so ni pe awon
obinrin olorin ki i gbe ile oko, sugbon ileri ti mo se fun won ni pe temi ko ni
i ri bee rara. Mo dupe lowo Olorun pe won pada gba fun mi, mi o si doju ti won
lori adehun ti mo se fun won.
OJUTOLE:
Odun wo le se rekoodu akoko, kin ni oruko e ?
Alaaja
Rukayat Gawat: Imole la pe oruko e, odun 2009 lo jade, a si dupe lowo Olorun pe
alubarika nla wo o. Kaakiri ni won ti gbo orin naa, koda to fi de ile Hausa.
OJUTOLE:Awon
isoro wo le doju ko nigba ti e bere?
Alaaja
Rukayat Gawat: Ko fi bee si isoro,se e mo pe ohun ti Olorun atawon obi eeyan ba
ti fowo si bii idan lo ma n ri. Ohun ti mo maa n so fawon eeyan ni pe sa deede
loro mi dola, oro mi dabi ojo to n ro ti ko su ni.
Rekoodu mi akoko yen lo je ki
n mo pe awon eeyan nifee mi. Leyin e ni mo se rekoodu ‘My Father, Arinakoore, Temitope , bee ni mo ti se
rekoodu alasepo pelu opo awon olorin musulumi. Eyi to wa nita bayii la a pe ni ‘Ogo
Tuntun’
OJUTOLE:
A gbo e tun n se nnkan mi-in yato si ise orin?
Alaaja
Rukayat Gawat: Bee ni, mo n ta awon aso ti won n pe ni voil lace, senegales,
atawon ohun eso ara mi-in, Ojota nileese wa.
A si tun sese si ileese ti a ti n se omi inu ora ati omi inu ike, Spring
Water loruko omi wa.
OJUTOLE:Pupo
ninu awon ololufe yin ni ko mo ibi ti won ti bi yin atawon ileewe ti e lo, e
salaye e fun wa ibi ti e ti se wa.
Alaaja
Rukayat Gawat: Omo Eko ponbele ni mi,ileewe alakobere Olusi to wa ni Isale-Eko
ni mo ti kawe alakobere, mo lo ileewe girama Sura Dolphin High School, mo tun
gba iwe eri digiiri nileewe yunifasiti Olabisi Onabanjo to wa ni Ago-Iwoye,
nipinle Ogun, imo nipa ise iroyin ni mo
se jade nibe.
OJUTOLE:
Ki lo waa de ti e ko ya sidi ise iroyin, to je pe idi orin le ya si?
Alaaja
Rukayat Gawat: Baba mi lo fi tipa mu mi lati kawee, emi o feran ise alakowe
rara, Mo lo sileewe lati te baba mi lorun ni, sugbon mo je ki won mo pe ise orin
lo wu mi lokan.
OJUTOLE:
N je o wa ninu awon omo yin,ti won fife han si
ise orin
Alaaja
Rukayat Gawat: Gbogbo won ni feran ise mi,awon ni ololufe mi akoko, ti won koko
maa n gba orin mi.
OJUTOLE:
Ti won ba n daruko awon olorin Islam ti imura ba ti esin mu daadaa, eyin ni won
yoo koko mu, ki lode eyin ki I toju-tomu bii awon yooku yin ti e jo n korin?
Alaaja
Rukayat Gawat:Emi ko feran iru nnkan beeyen ni lati kekere mi ni mo ti korira
kaa maa toju-tomu, o te mi lorun bii Olorun se da mi, ko digba ti a ba kun
nnkan soju ka too rewa.
No comments:
Post a Comment