IROYIN YAJOYAJO

ipolowo

Friday, 21 June 2019

OPE O:AYANGBAJUMO, GBAJUMO ONILU SEGBEYAWO ALAREDE L'AMERIKA,

Ojo nla ti gbajumo ti obinrin onilu nni, Queen Eniola Abiodun Lias ti gbogbo aye mo si Ayangbajumo ko le gbagbe boro lojo Tosde, ana yii. Ojo naa losere nla tawon eeyan feran daadaa yii segbeyawo alarede niluu Newyork, lorile-ede Amerika pelu ololufe e.

Ohun to tun je kinu obinrin yii dun daadaa ni pe ojo to diyawo tuntun yii naa layajo ojoobi e, eyi to tumo si pe idunnu subu layo fun un lojo yii.


 
Lasiko to n soro nipa ohun ayo to sele si i yii, Ayangbajumo ni: Inu mi dun loni-in, ebun ti enikan ko fun mi ri laye ni ololufe mi fun mi,  o gbe niyawo niluu oba lojo ayeye ojoobi mi. Latigba ti Ayangbajumo ti gbe igbeyawo e yii sori ero ayelujara lawon eeyan ti n ki i ku oriire.

Ojutole naa ba Ayangbajumo dupe lowo Olorun fun oore ayo to sele si i yii, Olorun yoo fi alubarika si i. 

No comments:

Post a Comment

Adbox