IROYIN YAJOYAJO

ipolowo

Tuesday, 25 June 2019

APONLE ANOBI TU ASIIRI NLA: PASUMA LO KOKO SO ASOTELE FUN MI PE MAA KORIN

Latowo Taofik Afolabi
Okan pataki ninu awon aafaa oniwaasi ati olorin taye n fe lorile-ede yii ni, Alaaji  Basit Katibi Bello ti gbogbo aye mo si Aponle Anobi. Bi okunrin omo bibi ilu Ibadan se n rowo mu laarin awon aafaa oniwaasi, bee lo n se daadaa ninu awon olorin Islam ti won wa lorile-ede yii.

Bo tile  je pe opo lo mo olopolo pipe ti orin re ma n wo akinyemi awon ni Aponle Anobi, sugbon ko seni to mo boro orin to n ko yii se je, asiiri ti Ojutole fee tu fun yin ree.

Nibi ayeye olodoodun ti gbajumo olorin Islam nni, Alaaji Sarafdeen Sulaiman tawon eeyan Albushran to pe ni 'Albushrah Day 2019' ni Aponle Anobi ti tu asiiri bo se di olorin. Ohun to sele ni pe Aponle Anobi to je arowaasi agba fun Sheik Muydeen Ajani Bello ni Albushrah pe lati ba a dari ayeye nla to se yii, nibi ti okunrin naa ti n dari eto naa lo ti so pe  oun  ni i lokan lati korin laye oun, o ni waasi lo wu oun lokan lati se jeun laye oun, sugbon nibi ayeye kan tawon ololufe gbajumo osere fuji nni, Alaaji Wasiu Alabi Pasuma se toun soro nibe lojo naa ni Pasuma ti so o loju gbogbo eeyan pe oun yoo korin. Aponle Anobi ni se Pasuma ro oun pe koun naa maa korin nigba to gbo awon waka olowo iyebiye to jade lenu oun.

O ni a fi bii eni pe Olorun gba enu Pasuma soro lojo yii, latigba naa lo so pe orin ti wa lokan oun to fi di ohun ti oun ko la bayii. Aponle Anobi ni lati femi imoore han si asotele ti Pasuma so foun lojosi lo je koun forin ye e si i lasiko ti irawo osere fuji naa sayeye aadota odun.

Sugbon, o ni majemu ti oun se ni pe oun ni bawon korin jeun lori siteeji,bi ko se pe koun maa gbe rekoodu jade.

Ju gbogbo e lo, Aponle Anobi ti so pe Pasuma ko lo koko so asotele foun pe oun yo korin laye oun.   

No comments:

Post a Comment

Adbox