IROYIN YAJOYAJO

ipolowo

Monday, 17 June 2019

OJO SANNDE TO N BO YII NI ALBUSHRAH, OLORIN ISLAM YOO SAYEYE NLA L'EKOO

Gbogbo eto lo ti pari bayii lori ayeye onibeji ti gbajumo olorin Islam nni, Alaaji Sarafadeen Sulaiman ti gbogbo aye mo si Albushrah fee se. Ojo Sannde to n bo yii layeye naa, iyen ifilole fidio rekoodu 'Ojo Eye mi' ati fifun awon eeyan lami-eye.

Inu gbogan 'Balaway Event Centre' to wa legbee China Town ni Oworosoki layeye naa yoo ti waye. Eni ti yoo se waasi lojo naa Sheik Jamiu Sulaiman Asanbe, imaamu ilu Agelete-Ikoyi. Mama ojo naa ni: Alaaja Tawakalitu Abiola Oladosu.

Lara awon olorin  ti won reti nibi ayeye naa ni: Alaaja  Rukayat Gawat-Oyefeso, Alaaji Qumardeen Odulami Ayeloyun, Alaaja Amdalat Bello ti gbogbo aye mo si Aweni Oniwaka. Eni ti yoo dari ayeye naa ni: Alaaji Basit Katibi Aponle Anobi.

No comments:

Post a Comment

Adbox