IROYIN YAJOYAJO

ipolowo

Monday, 17 June 2019

GONGO SO LOJO TI GBAJUMO AAFAA ONIWAASI, SHEIK AINURIDOH FAWON EEYAN JOYE, WON TUN SE IKOWOJO MOSALAASI NLA
























Ojo nla ti gbajugbaja aafaa oniwaasi nni, Fadilat Sheik Muritadoh Abolaji Ainuridoh ko le e gbagbe boro lojo Abameta, Satide to koja yii, idi ni pe ojo naa ni aafaa nla naa fi awon eeyan nla nla joye, ti won tun se ikowojo mosalaasi nla ti won pe ni 'Eleyele Central Mosque' to wa ni Owode-Elede lona Ikorodu, nipinle Eko.

Bo tile je pe ojo ro pupo lojo naa, bamubamu nibi ti won ti sayeye naa kun fun  awon eeyan pataki atawon ero, ko seni to woju ojo yii, won ko tie se bii eni pe kinni ohun n pa awon.

Adura ni won koko fi bere eto naa, leyin ni won tun fadura ranti Baba Adinni Mosalaasi Eleyele to dologbe, Alaaji Bisiriyu Obalowu Ayinla. Leyin adura pataki ni won foju awon ti won joye lojo yii han, ko too di pe eto naa bere ni pereu. Aafaa oniwaasi to gbajumo daadaa nni, Fadihilat Sheik Buhari Omo Musa lo se waasi lojo naa, ti Alaaji Ahmod  Asbiyallahu Kewuyemi forin aladun da awon eeyan lara ya.

Awon to joye lojo naa ni: Alaaji Zakaryah Ajao Owolobai Idofian( Seriki Adinni), Alaaji AbdulMujeeb Hassan ( Muazinu Agba) Alaaji Monsuru Agbaje(Akeweje Adinni) Alaaja Rasheedat Zakaryahu Idofian(Borokinni Adinni) Alaaja Afusat Abdrasheed Olayode( Alatunse Adinni) Alaaji Baba Alade (Mogaji Adinni) Alaaja Maryam Agbolade Owolewa(Arowosadinni) Alaaja Simiat Iya Bukky ( Iya Sunna) Alaaji Abdulrasheed Olawale( Alaranse Adinni) Alaaji Isiahq Atanda (Saraki Adinni) Alaaja Mufuliat White(Imole Adinni)

 

 

No comments:

Post a Comment

Adbox