IROYIN YAJOYAJO

ipolowo

Sunday, 2 June 2019

LEYIN TI ARA RE YA TAN, BABA SUWE LOO DUPE LOWO ENI-OWO ESTHER AJAYI TO FUN UN NI MILIONU MEWAA NAIRA

Leyin bii ojo meloo kan to  de lati orile-ede Amerika to ti loo gbatoju, agba-oje osere tiata Yoruba nni, Alaaji Nurudeen Babatunde Omidina ti gbogbo aye mo si Baba Suwe ti loo dupe lowo Eni-owo Esther Ajayi to bu un ni milionu mewaa naira, to tun san owo baalu to gbe e lo si Amerika fun itoju.

Ile Igbafe 'Sheraton Hotel' to wa ni Ikeja, nibi ti Mama Esther Ajayi ti n se ipade pelu awon omo ijo alaso funfun kan ni Baba Suwe ti loo ba a. Oun ati omo e, Sola ati Adegboyega aburo e ni won jo lo.

Baba Suwe, ninu oro e lo ti dupe lowo Mama Esther Ajayi fun oore nla to se fun un yii, bee ni ojise Olorun naa lo asiko naa lati sadura fun Baba Suwe.   



No comments:

Post a Comment

Adbox