IROYIN YAJOYAJO

ipolowo

Saturday, 15 June 2019

IBERU OLORUN ATI IWA OMOLUABI LO SO WA DOGAA NI AL-HATYQ TRAVEL AND TOURS LIMITED-ALFA SEMIU LASTBORN

Lojumo to mo loni-in, okan pataki ninu awon ileese to n ko awon eeyan lo si umra ati haji tawon araalu fokan tan pe won ko ni i ja awon kule ni nileese Al-Hatyq Travel and Tours Limited, ti Otunba Mutiu Badmus ti gbogbo aye mo si Wale Ticket je oludasile ati oga-agba e. Awon eeyan to le ni ogoji nileese naa ko lo si umra aawe to koja yii.

Laipe yii ni oga eka igbokegbodo ileese naa, Alaaji Semiu Lastborn toun naa sese de lati umra ba Ojutole soro, lara ibeere ti a bi i ni pe ki lode to je pe ileese Al-Hatyq lo gba ipo kin in ni ninu awon ileese yooku, idahun to fun wa ni pe iberu Olorun tawon fi saaju awon ohun ti awon n se nileese awon pelu  awon iwa omoluabi tawon mu ni koko lo je kawon eeyan feran lati maa ba awon rin irinajo.

Okunrin yii nitori pe awon ki i lu jibiti tabi ja awon onibaara awon kule lo je kawon olorin nla bii:Alaaji Wasiu Alabi Pasuma, Alaaji Sefiu Alao Adekunle, Alaaja Modinat Barytide,  Alaaja Maryam  Akiki, Alaaja Fatmo Iyawo Facebook, Amir Oloriire, Alaaja Aminat Omotayebi,Alaaji Giwa Ebunlorin atawon mi-in buwo lu u pe ileese awon lo n saaju awon ileese yooku to n ko awon eeyan lo si umrah ati hajii.

O fi kun oro e pe aaye ti si sile bayii fawon eeyan to ba fee ba awon lo si Meka odun yii, o ni bo tile je pe milionu meji tabi ju bee lo lawon ileese yooku gba fun Meka,sugbon milionu kan aabo lawon gba ni tawon nitori pe alubarika lawon n wa lodo awon.





 

No comments:

Post a Comment

Adbox