IROYIN YAJOYAJO

ipolowo

Monday, 10 June 2019

GBAJUGBAJA AAFAA ONIWAASI NNI, SHEIK AINURIDO ABOLAJI KILO FAWON IRAWO OLORIN ISLAM

Okan pataki ninu awon aafaa oniwaasi ti won loruko gidi lorile-ede yii ati loke okun ni Sheik Musa Abolaji Ainuridon, kaakiri ibi gbogbo lorile-ede yii ati loke okun ni baba naa ti gbe ise Olorun de. Sugbon, aafaa oniwaasi nla yii ti fi ikilo nla ranse sawon gbajumo olorin Islam lorile-ede yii.

Nibi ayeye oniberin ti olorin islam to sese n koge agba bo, Hajia Khadija Iyawo Anobi se lanaa, ojo Aiku, Sannde, ni Ainurido ti ju ikilo nla yii sile fawon irawo akorin esin yii.

Lasiko ti aafaa tawon eeyan feran daadaa yii n se waasi lo ti so pe ohun to buru jai ni bawon to ti loruko ninu awon olorin Islam ki i se ran awon to n bo leyin lowo. O ni gbogbo awon to ti dide lonii lo je pe ibi kan lawon naa ti bere, sugbon won o ki n ranti ibi ti won bere mo,to je pe faari ni won yoo maa se.

Ainurido waa ro awon ti ko ti i goke loni-in, kawon naa ma gbagbe ibi ti wo ti dide tawon naa ba di oloruko nidii ise orin ti won yan laayo. 




No comments:

Post a Comment

Adbox