Ki i se ohun ti eti ko gbo ri pe agba-oje osere tiata
apanilerin-in, Alaaji Nurudeen Babatunde Omidina ti gbogbo aye mo si Baba Suwe
ti de lati Amerika to ti loo gbatoju, sugbon, opo ni ko mo bi itoju naa se lo, nitori e ni
Ojutole se wa Adimeru oko Moladun Kenkelewu lo. Ninu iforowero ti a se fun
gbajugbaja osere nla yii lo ti
salaye bo se gba itoju, awon to ran an lowo,
paapaa ojise Olorun, Mama Esther Ajayi, Asiwaju Bola Ahmed Tinubu atawon nnkan
mi-in ti ko so fun oniroyin kan. Bi iforowero ohun se lo ree o
OJUTOLE: Fun akosile, e daruko yin fun wa
BABA SUWE: Emi ni Babatunde Omidina ti gbogbo aye mo
si Baba Suwe. Omi-o-se-e-ta-ni-koko- onipariesin, Eranku-niluu-airobe.
OJUTOLE: A dupe lowo Olorun pe e ti pade lati ilu Amerika
ti e ti loo gbatoju, opo awon eeyan ni won fee gbo lati odo yin, a fe ki e so
iriri yin fun wa nigba ti e n gba itoju lowo
BABA SUWE: Nigba ti mo debe, mo mo pe ilu oba ni mo
wa, o yato sibi daadaa, otutu po lasiko naa, se e ri omo to jokoo yii( o nawo
si i) Adesola Morenikeji Omidina omo gidi ni, o toju mi daadaa, oun lo maa n we fun mi, toun seto ounje mi latodo mama e wa
si odo mi, omo alalubarika ni.
OJUTOLE: Foto kan jade lori ero ayelujara ti dokita oyinbo kan n to ese
yin, e salaye fun wa nipa itoju ti won se fun yin nibe.
BABA SUWE: Okan lara awon dokita to toju mi niyen,
gbogbo ohun to ye ki n se ni mo se, itoju si te e siwaju bi mo se pada wa si
Naijiria, mo dupe lowo Olorun pe o gba gbogbo akoso. Ti mo ba ri bi ara mi se
ri, o se e se ki n tun pada lo siluu oyinbo. Won gbinyanju pupo, Olorun naa ti
wa leyin, mo dupe gan-an. Mi o lo ju osu kan lo nibe.
OJUTOLE: Ko ju bii ojo meloo kan ti e debe lariwo nla gba ilu pe e ku, bawo
niroyin naa se ri lara yin?
BABA SUWE: O ya emi naa lenu pupo, ohun ti mo so
nipe, emi ko ti i setan iku, eni ti oju ba n kan, ko maa niso lorun. Se ni mo n
beere lowo ara mi pe o se waa je emi lawon eeyan maa n ro aburu si, o se je pe
nigbakigba ti mo ba lo siluu oyinbo ni won yoo so pe mo gbe kokeeni, mo ku
sohun-un. Mo waa ro o pe boya ohun ti Olorun fi n ko mi yo niyen, oro mi dabii
eni ti omo araye ko je ko gbadun, o san ju eni ti won gbagbe e lo.
OJUTOLE: Bayii ti e ti de, kin ni kawon ololufe yin maa
reti latodo yin?
BABA SUWE: Pelu iyonda Olorun, mi o nise mi-in to ju
ise tiata lo, mo si maa se, ti n maa dara si i, ara n be ninu mi, o wu mi lati
se ise mi-in. Eni to koko waa ba mi pe oun fe ki n se fiimu foun, ohun ti mo so
fun un ni pe se o ni milionu lona igba naira ti yoo fun mi lowo nitori pe Baba
Suwe ti won loja bayii, eni ti won lo ku
ti ko ku, o gbodo gba owo nla lowo eni to ba fee gbe fiimu e jade. Lagbara
Olorun fiimu kan n bo latowo ileese ‘Twenty Second Global Studio’, omo mi
Adesola Omdina lo ko o, oun naa lo dari e ‘ ‘Turning Point’ la pe akole e, ede
oyinbo ati Yoruba la a fi se. Baba Suwe dara ninu e, fiimu naa ni ise akoko ti
mo se latigba ti mo de lati Amerika.
OJUTOLE: Ko si
bi a se fee daruko Baba Suwe lasiko yii,
ti a ko ni i daruko ojise Olorun, Mama Esther Abimbola Ajayi si I. Ki le fee so
nipa won?
BABA SUWE ATI OJUTOLE LEYIN IFOROWERO |
Eeyan gidi ni won, nigba ti mo de
lati Amerika, won ni ki n yoju sawon, nigba ti mo de odo won, mo ba awon eeyan
repete lati gbogbo ipinle lorile-ede yii, nigba ti mo n gbo awon oro olowo
iyebiye to n jade lanu won, emi gan-an ko le e dide nibi ti mo wa, oro won wo
mi lara pupo. Mo ni Olohun, Olohun, eni to ba ri won ko ni I mo pe mama ti
Olorun n lo fun wa ree, eni naa ko ni i mo pe mama to n fi owo saanu gbogbo
eeyan ree. Ti Olorun ba saanu fun eeyan, koun naa saanu omolakeji ohun ti mama
n se niyen, ki i se emi nikan ni won soore fun, atomode, atagba ni won n ran
lowo.
Ohun ti mama n so ninu iwaasu won ju ni aanu, mo ro gbogbo
eeyan pata pe ki won loo sori eka ayelujara to n je istagram lati loo gbo awon
iwaasu mama, e tele won lori istagram pelu oruko yii.lord_christ_generation, ki
omode ati agba loo darapo mo won lori istagram fun awon iwaasu ti yoo tun aye
won se atawon ise iyanu ti Olorun towo won se. Oruko soosi won ni ‘Lord of
Christ Generation, ilu London lo wa, sugbon kaakiri agbaaye ni won maa n gbe
iwaasu won lo.
OJUTOLE: E je ka sawada die, nigba ti milionu mewaa naira
ti won fun yin wonu akanti yii, ti e gba alaati lori foonu yin, bawo lo se lara
yin?
BABA SUWE: Haa, bi igba ti giri mu eeyan, ori mi koko
daru, mo koko beere lowo ara mi se Naijiria kan naa la wa, abi Naijiria mi-in,
awon eeyan da mi lohun pe Naiiria yii naa ni. Nigba ti mo ba won soro, haa,
ajanaku koja mo ri nnkan firi, ti a ba rerin, a o mo pe a ri erin, mama Esther
Ajayi somoluabi pupo, bee ni oko won Dokita Ajayi, baba daadaa, alaanu eeyan ni
won, bee lawon osise atawon omo won, gbogbo won pata ni won fife han si mi
nigbakigba.
OJUTOLE: Awon eeyan wo le tun fee dupe lowo
won?
BABA SUWE: Awon eeyan po, awon eeyan to feran mi po,
Amerika ni o, London ni, Germany, Italy France ni, Naijiria n ko, gbogbo won
won n pe mi, ti won sadura fun mi, ti won fun mi lowo. Eeyan mi kan wa ni London, Looya Daniel loruko e, awon ni won koko gbe oro mi ka ori, won feran
mi gan-an. Bee ni Asiwaju gbogbo Afrika, aburo mi Bola Ahmed Tinubu Jagaban.
Aburo mi ni Bola, owo to ye ki Olorun gbe fun emi egbon e lo gbe fun un, mo wa
a ni aburo mi lo lowo to yii, ki Olorun ma gba owo naa lowo e nitori pe alaanu
gbogbo aye ni, gbogbo eeyan lo n soore fun. Bee ni egbe TAMPAN, won gbiyanju
nigba ti ara mi ko ya, a jo de LUTH ni, awon ni won gbe mi lo, mo dupe lowo
Olorun pe won ko gbe oku mi jade, won se gudugudu meje ati yaaya mefa loro mi.
Gbogbo won pata ni mo dupe lowo won latori aare to fi dori eni to kere ju ninu
egbe, ti mo ba ni ki n maa daruko leyokookan, ile yoo su. Bee lawon TAMPAN
Amerika naa, won ran eeyan wa, won tun fowo ranse si mi.
Bakan naa ni mo dupe
lowo igbakeji aare orile-ede yii, Ojogbon Yemi Osibajo, mo dupe lowo ijoba
apapo naa ati minisita fun eto ilera lorile-ede yii. Bee ni mo tun dupe lowo
awon omo egbe ‘Achievers Corporate Club’ to je egbe mi, mo dupe lowo ore mi pataki,
Ogbeni Gbade Oguntoyinbo, ore bii omo iya ni, o se pupo loro mi, mo dupe lowo
Ogbeni Tula of London,Iya Lara ni London, Anti Ann ni Rhodes Island, ounje
Pataki ni won gbe fun mi losibitu, mo dupe lowo Segun Rasco, oyinbo olohunje ni
Amerika niyen, odo e ni mo koko de si, mo dupe lowo gbogbo won. Awon osere ni
Amerika gbiyanju, won gba pe oba lo de sodo awon.
Mo dupe lowo omo mi Yomi Fabiyi, o se daadaa fun mi, ki
Olorun ba mi se daadaa fun un.
Bee ni mo dupe lowo iyawo mi, o se pupo loro mi, o fife han
si mi,emi naa si nifee e, mo maa toju e daadaa. Nipari, mo sadura fun mama mi
Esther Ajayi gbogbo ohun to da a ninu aye won ko ni I dibanuje, idaamu aye ko
ni I je ti won, won ko ni pade agbako, won ko ni i te oju ile mole, lojo kan a
wa naa n bo wa si London lati waa dupe
lowo won.
( Omo e, Adesola Omidina naa dupe lowo gbogbo awon eeyan) Loruko gbogbo ebi Omidina ni mo n fi dupe
lowo gbogbo eeyan, to ba rorun fun gbogbo wa ni a o gba lo ori telifisan naa
lati dupe, gbogbo toro ati kobo ti o wole la dupe lowo gbogbo awon eeyan to fun
wa, eni ti won ko ba daruko e, ko ma binu, a mo oore ohun ti e se fun wa, koda
awon to je pe adura ni won fi ran wa lowo,a dupe lowo gbogbo won pata.
No comments:
Post a Comment