IROYIN YAJOYAJO

ipolowo

Wednesday, 22 May 2019

SAHEED OSUPA TU ASIIRI IDI TI KO SE BA AWON OMO DAUDA EPO AKARA SE PO

Ninu iforowero ti gbajumo osere fuji nni, Alaaji Saheed Osupa se pelu ileese telifisan BBC Yoruba lokunrin naa ti tu asiiri idi ti ko se ni ajosepo kankan pelu awon omo Oloogbe Dauda Epo Akara, toun naa je gbajugbaja olorin awurebe nigba aye e.

Okunrin kan to je ololufe Saheed Osupa lo ro osere omo bibi ilu Ibadan naa pe ko gbagbe ohun to ti sele, ko ma ta awon omo Epo Akara nu,paapaa bi Olorun se ti gba adura re nidii ise orin.

Nitori ohun ti eni yii so ni Osupa se so pe eni naa mo ohun to n sele laarin awon ati pe oun ko fee so oro naa sita, sugbon pelu ibi toro de duro yii, oun setan lati je ki awon eeyan mo boro naa se je.

Osupa ni baba oun, Oloogbe Moshood  Okunola, toun naa je olorin fuji lo salaye ohun tawon Epo Akara foju re ri nidii ise orin, ti baba oun fi sa kuro nibe kolojo too de, sugbon oun ko ka itan baba oun yii so foun si rara, o loun ro pe asodun lasan lo so, afigba ti okiki oun buyo diedie toun pade Epo Akara ti baba olorin awurebe naa so foun bayii pe ' Saheed, omo Moshood, iwo naa tun n korin'. Oro ti baba yii so lo je koun gba pe looooto ogun nla ni won ba baba oun fa, nitori e loun  fi yera fawon omo Epo Akara, nitori aburu ti baba won se fun baba oun.  


No comments:

Post a Comment

Adbox