IROYIN YAJOYAJO

ipolowo

Tuesday, 14 May 2019

OPE O: AGBA OSERE TIATA, RAMMY SHITA-BEY DI ASOJU ILEESE ILOSHE PROPERTY AND INVESTMENT LIMITED, OKUNRIN NAA SO PE GBOGBO ARAALU NI YOO NILE LORI BAYII

Latowo Taofik Afolabi
Iroyin ayo to te Ojutole lowo bayii ni pe agba-oje osere tiata Yoruba nni, Alaaji Rammy Adebayo Shita-Bey, ti gbogbo aye mo si Adebayo Omo Iya Aje ti di asoju ileese to n ta ile ati ile, iyen 'Iloshe Property and Investment Limited to wa ni Iyana-Ipaja,l'Ekoo. Ana, ojo Aje, Monde ni won siso loju okunrin omo bibi ilu Eko naa gege bii asoju ileese yii.

Pelu ipo to sese gba yii,  Rammy to ti figba kan se gomina egbe osere tiata ANTP nipinle Eko ni yoo maa satona bi oruko ileese to je asoju won yii yoo se gboroo si i, tawon onibaara won yoo poju ti tele lo.

Lasiko to n ba Ojutole soro, akowe iroyin fun ileese Iloshe, Ogbeni Ademola Sanyaolu so pe inu awon dun lati yan Remmy Shita-Bey gege bii asoju awon, o ni okunrin naa ki i se osere ti oruko re ti baje laarin awon elegbe e ati pe enikan to mu ise e ni koko ni. O ni pelu bo se je asoju awon yii, okan awon bale pe kaakiri  agbaaye ni yoo polongo ileese Iloshe de. O ni gege bi osere to kun ju osuwon, okan awon bale pe o to gbangba sun loye pelu ipo to gba yii.

Bakan naa lo fi kun oro e pe gbogbo ile awon ni ko ni wahala awon omo onile ninu rara, nitori pe gbogbo awo ebi to ye kawon ri lori awon ile yii lawon ti ri pata, bee lo so pe aaye sisan owo diedie wa fun awon ti ko ba le sanwo leekan naa.Odun meji gbako lo so pe Rammy yoo fi je asoju awon, ti ko si letoo lati je asoju ileese to n se nnkan ti awon n se fun odun meji yii.

Ninu oro e tie, Rammy ni oun ti wadii ileese yii daadaa ko too di pe oun gba lati bawon sise po, oun si ri i pe olooto ni won. O ni gbogbo aye lo mo pe oun ki i si nidii jibiti tabi ohun ti yoo mu

wahala ba awon eeyan. O ni saaju asiko yii lawon ileese ti won  n ta ile ti waa ba oun lati je asoju won, sugbon ileese Iloshe lokan oun mu. Bee lo so pe gbogbo ibi ti ile won wa loun ti de, toun si ri i pe ojulowo ni gbogbo ile won, ti ko ni wahala awon omo onile ninu, o ni gbogbo eni to ba ra ile lowo ileese Iloshe ni ko ni i kabamo lati bawon dowopo.

Okunrin yii waa ro gbogbo araalu lati waa soriire lodo awon Iloshe nitori pe ko seni to ba bawon dowopo ti yoo kabamo nitori pe opolopo anfaani ni won yoo ri nibe.       







No comments:

Post a Comment

Adbox