IROYIN YAJOYAJO

ipolowo

Tuesday, 14 May 2019

OJO NLA LOJO TI GBAJUGBAJA ONISOWO, ALAAJI RASAK AGBAOWO SE WAASI AAWE RAMADAN-BAMUBAMU LAWON EEYAN PATAKI PEJU-PESE SIBE

















LATOWO TAOFIKAFOLABI ATI TOYIN AGBOLADE

Ojo nla tawon musulumi nipinle Eko ko ni I gbagbe boro lojo Aiku, Sannde, ojo kejila, osu karun-un ti a wa yii. Ojo naa ni gbajumo onisowo nla nni, Alaaji Rasak Agbaowo se waasi aawe Ramadan to maa n se lodoodun.  Gbongan Hammond Hall to wa ni Ijegun ni waasi ohun ti waye.

Bawon aafaa nla –nla ti wa lori ijokoo lojo naa, bee lawon olowo atawon oloro bii: Oga-agba ileese Yoyo Bitters, Dokita Abiola, oga-agba ileese Oko Oloyun World-Wide, Alaaji Fatai Yusuff, Pasito Akin Fasawe,  Alaaji Abdulganiy  Akewusola, Olootu iwe iroyin Alariya Oodua, Pasito Kunle Babarinde atawon eeyan nla mi-in wa nibe.

Lara gbajumo osere tiata Yoruba ti won wa nibi waasi yii ni: Iya Awero, Nike Peller, Rammy Shita-Bey, Ojoge, Fathia Balogun, Kemi Korede, Sikiratu Sindodo, Alado, Ajobiewe, Yetunde Wunmi, Fiye, Azzes Ajobiewe, Wale omo Iya Awero, Taiwo Goslow atawon mi-in.

Lara awon olorin Islam ti won korin lojo naa ni: Iya-n-Ghana, Kifayat Singer, Rukayat Gawat ati Ere Asalatu. Awon gbajugbaja sorosoro ori radio nni, Ambasado Yomi Mate Ifa-n-kaleluyah ati Oloye Abiodun Adeoye Afefe Oro ni won dari eto naa.

No comments:

Post a Comment

Adbox