IROYIN YAJOYAJO

ipolowo

Monday, 13 May 2019

NINU OSU RAMADAN, HAJIA AZEEZAT OTIBIYA OLORIN ISLAM TU ASIIRI NLA FUN OJUTOLE

Lojokojo, nigbakigba ati nibikibi ti won ba n ti daruko awon obinrin olorin Islam ti won n se  daadaa lorile-ede yii, abi awon ti oruko won rinle daadaa, ohun to daju saka ni pe won yoo daruko Hajia Azeezat Lawal ti gbogbo aye mo si Otibiya si I, oodu lomobinrin yii laarin awon olorin nile yii, ki I saimo foloko.
Kinni kan wa a ni o, bi Otibiya se loruko ati okiki to laarin awon elegbe e, onisowo pataki ni, awon ohun eelo ara bii aso, bata, goolu atawon eso ara okunrin mi-in losere to rewa daadaa yii n ta.
Fun anfaani ati igbadun awon ololufe wa la se wa obinrin yii lo lati salaye irin-ajo de idi orin, awon ohun ti oju ri ati ohun to so o donisowo Pataki fun wa
Bi oko ko ba jina, ila ki I ko, e wa nnkan fidi le, tabi ki e fidi le nnkan lati ka iforowero raipe ti a se pelu Otibiya, gbajumo olorin Islam, to tun je onisowo pataki. E ma a ba wa ka lo
OJUTOLE:E salaye die fun wa nipa yin
Otibiya: Oruko mi ni Azezat Lawat tawon eeyan mo si Otibiya, omo bibi ilu Oke-Odan, nijoba ibile Yewa, nipinle Ogun ni mi. Idile oniyawo pupo ni mo ti wa.
OJUTOLE: Bawo le se bere ise orin?
Otibiya: Omo odun metala pere ni mo wa ti mo ti bere ise orin nigba ti mo wa ni ileekewu. Emi ni mo saaju awon elegbe mi,  awa la maa n se ipo kin inni nigba naa. Lati omo odun metala ti mo wa ni oruko mi ti n han ni Sango ti mo n gbe. Bi mo se to oju bo ni mo so fawon obi mi pe ise orin ni mo fee yan laayo, won ko tako mi, nigba ti won mo  pe nnkan ti mo n se lati kekere ni. Mo dupe lowo Olorun pe loni-in, ipo asaaju la wa naa wa ninu awon to n korin esin lorile-ede yii.
OJUTOLE: Bawo loruko Otibiya ti e n je se waye?
Otibiya: Lodun 2010, mo saisan kan nigba naa, ti Olorun lo aafaa kan fun mi, aafaa naa lo beere lowo mi pe se bi olorin ni mi, mo ni bee ni, o ni ki n ma je Ayekooto ti mon je mo, ki n maa je Otibiya, nitori pe lati asiko naa, gbogbo isoro ati idaamu mi ni yoo  biya. Bo se di pe mo yi oruko mi pada si Otibiya,kuro ni Ayekooto ti mo n je tele niyen.
  OJUTOLE: Imoran wo le fee gba awon to n bo leyin yin?
Otibiya: Ki won mu ise won ni koko, ki won ma sole, ki won si ni iteriba fawon asaaju won, lara ebun ti Olorun fun mi to n ran mi lowo doni-in lebun iteriba ti mo ni, awon eeyan si tori e feran mi daadaa. Mo ro awon to n bo lona pe ki won ma yaju sawon ara isaaju, dajudaju awon naa yoo ga a lol.      
   

No comments:

Post a Comment

Adbox