IROYIN YAJOYAJO

ipolowo

Tuesday, 23 April 2019

OPE O: BABA SUWE TI BALE S'AMERIKA FUN ITOJU TO PEYE, OKUNRIN NAA DUPE LOWO GBOGBO OMO NAIJIRIA

Iroyin ayo ree fun gbogbo awon ololufe  gbajumo osere alawada nni, Alaaji Nurudeen Babatunde Omidina, ti gbogbo aye mo si Baba Suwe, okunrin omo bibi ilu Ikorodu, nipinle Eko naa ti bale si orile-ede Amerika fun itoju to peye lori aisan ito suga to n yo o lenu.

Ojutole gbo pe okan ninu awon omo e, Sola toun naa gbe l'Amerika to ti wa ni Naijiria lati ojo meloo kan seyin nitori ara baba re ti ko ya yii lo mu Baba Suwe lo si Amerika, ileewosan nla kan to wa ni Rhode Island losere apanilerin-in  ti n gba itoju bayii.

Gbara ti okunrin yii kunle si Amerika,leyin ti won ti koko toju e nileewosan ijoba 'LUTH' lo dupe lowo gbogbo awon omo Naijiria fun iranlowo ti won se fun un. Lara awon eeyan to daruko ni woolli agbaaye nni, Mama Esther Ajayi to ni ijo 'Love of Christ Generation Church' to wa ni London atawon eeyan mi-in.

Bakan  naa lo dupe lowo awon osere egbe e, paapaa awon asaaju egbe TAMPAN fun aduro ti won. Gbara ti ara Baba Suwe ba ti ya
daadaa, ni yoo pada si Naijiria lati maa se ere tiata to so o dolokiki. 

No comments:

Post a Comment

Adbox