IROYIN YAJOYAJO

ipolowo

Wednesday, 10 April 2019

ERIN WO: AGBA ONKOWE NNI, ALAGBA OLADEJO OKEDIJI, FAYE SILE

Aaro kutu owuro yii ni koowe ke, koowe to ke ohun, ko fohun ire, iku wole were, o mu agba onkowe nni, Ojogbon nla ninu awon onimo, Alagba Oladejo Okediji lo. Bee, aisan ko se baba yii, sugbon oto niku, oto laisan, oto ni olojo. 

Gege bi a se gbo, lojiji ni kinni ohun ki ojulowo omo Yoruba yii mole, loro ba di digbadigba, ka too seju pe e, elemi-in ti gba a, baba Okedeji deni to n ba ebora jeun.

Latigba tisele aburu yii ti sele, lawon eeyan kaakiri agbaaye ti n kedun eni ire to lo yii. Adura wa ni pe ko se iku nisinmi fun baba olopo pipe to lo yii.  


Lara awon iwe ti  Ojogbo Okediji ko nigba aye won ni: AGBALAGBA AKAN, AJA LO LERU, KARIN KA PO, RERE RUN, ATOTO ARERE, AAJO AJE, AARO OLOMOGE, SANGO.

No comments:

Post a Comment

Adbox