Lati le mu itesiwaju ba oro aje awon
omo Yoruba ati ki asa ati ese wa maa ba parun, iwe iroyin YORUBA tuntun kan ti jade bayii si igboro, iwe iroyin
Asejere ni won n pe e, odo awon to maa n ta iwe iroyin iyen fendo le o si ti
maa ri ra.
Gege bi a se gbo, iwe iroyin yii ni
yoo je akoko ti yoo maa so nipa bi nnkan se n loo si nipa okoowo, oro aje, ohun
to n lo lagbo osere to lokiki nidi ise tiata ati orin, ti won tun je ojulowo
onisowo.
Awon gbajumo onisowo, ti won ni
okoowo-nla yoo tun maa lo anfaani lati gbe oro aje won jade nipa bi won se bere
ati ibi ti won ba okoowo won de ati ona ti won le gba se asejere nipa ise naa..
Bee la tun gbo pe gbogbo awon araalu lo tun wa fun latile fi
tun ni imo kikun nipa ede Yoruba ati pe ilosiwaju nla ni yoo mu ba ile Yoruba
paapaa lori igbelaruge oro aje atawon ise abinibi ile omo Oduduwa ti ko gbodo
dawati lawujo wa.
Won ni osoosu niwe iroyin yii naa yoo maa jade lati akoko yii
lo Eyi to si ti wa nita bayii tawon araalu ti n tu yaya sita lati ra.
No comments:
Post a Comment