Ojo nla ti gbogbo awon omo ilu Olota nijoba ibile Idagbasoke Agbado Oke-Odo ko le gbagbe boro lojo Tosde, ojo kefa osu kejila odun, ojo naa ni gbajumo ojise Olorun nni, Daniel Ebelamu Ajibose gba opa ase gege bii baale ilu naa, bamubamu lawon omo ilu yii kun gbongan ijoba ibile Alimoso ti won ti jawe oye le baale tuntun yii lori.
Ohun too tun waa je kojo naa larinrin pupo ni pe awon idile keji ti won tun oye pelu ebi Ajibose naa wa nibi ayeye igbopa ase yii, gbogbo won ni won so pe awon fowo si i pe ki Daniel di baale ilu Olota, tinu gbogbo won si dun lojo yii. Awon oba alaye marun-un ni won jawe oye le baale tuntun yii lori, ti won si tun rojo adura fun un.
Leyin iwure ati ewe oye yii ni won gbe iroyin ayo yii gba ilu Olota lo,ti gbogbo ilu naa si larinrin lojo yii.
Ti e ko ba gbagbe, ninu iwe ti ijoba ibile Alimoso fi sowo si i lojo ketadinlogun osu kewaa odun yii ni akowe ijoba ibile ohun, Olaleye M.A ti fidi e mule wi pe, Ogbeni Daniel Ebelamu Ajibose gan-an ni igbimo to n ri si oro oye nijoba ibile ohun fowo si gege bi baale tuntun niluu Olota.
Ninu iwe ohun ni won ti fidi e mule wi pe, awon meji ni ebi Adibo fa kale, Ogbeni Fehintola Akanni ati Daniel Ajibose, ti won jo du oye ohun, ki o too ja mo Ajibose lowo, leyin ti igbimo to n ri si oro oye se iwadii to peye.
Odun 1967 ni won bi Oloye Daniel Ebelamu Ajibose, akosemose onimo ero ni, iyen Enjinnia, bee lo tun je ojise Olorun to maa n se waasu ati ihinrere nipa Olorun ati Jesu Olugbala.
No comments:
Post a Comment