IROYIN YAJOYAJO

ipolowo

Thursday, 4 October 2018

EYI NI BI SUNKERE-FAKERE OKO SE KO IDAAMU NLA BA AWON ARA IKORODU

Lati bii ose meloo kan seyin lawon ara Ikorodu ti n foju wina idaamu sunkere-fakere oko ti won n pe ni go-si-loo, kinni ohun si ti fi aye su pupo ninu won.

Ojutole gbo pe ojuona to baje ni Kosofe ati Mile 12 lo fa wahala sunkere-fakere ohun, eyi to je ki go-si-loo ohun bere lati Majidun to si kanle si Mile 12 lohun-un.


A gbo pe o kere tan awon moto n lo to wakati meta si merin ninu sunkere-fakere ohun, awon osise LASTMA to n wa lojuona yii ko si ri kinni kan se  si i.

Pupo ninu awon eeyan to ba Ojutole soro ni won binu sijoba ipinle Eko pelu bi won se n wo oju-ona to baje ohun niran, ti won ko tie ya si i rara. Won ni se nijoba se bi eni pe awon ara Ikorodu ko si lara ipinle Eko.

Aworan latowo Rilwan Babalola   

No comments:

Post a Comment

Adbox