IROYIN YAJOYAJO

ipolowo

Sunday, 30 September 2018

SANWO-OLU KO LE E DI GOMINA EKO, O TI SEWON RI L'AMERIKA -AMBODE LO SO BEE

Gomina ipinle Eko, Ogbeni Akinwunmi Ambode ti ju bombu oro si alatako e ninu ibo abele gomina ipinle Eko, iyen Babajide Sanwo-Olu. O ni okunrin naa ki i se eni tawon ara Eko gbodo dibo fun gege bii gomina ipinle Eko, nitori pe okunrin naa ti sewon ri l'Amerika.

Lasiko to n ba awon oniroyin soro losan yii ni Ambode  so pe Sanwo-Olu ki i se eni to letoo lati di gomina ipinle Eko, Ambode ni alatako oun ti sewon ri l'Amerika leyin igba tawon olopaa mu un pe o na ayederu owo dola nile igbafe.

No comments:

Post a Comment

Adbox