IROYIN YAJOYAJO

ipolowo

Thursday, 13 September 2018

NITORI WAHALA TI TINUBU KO BA A, PDP NI KI AMBODE MA A BO LODO AWON, SUGBON JIMI AGBAJE ATI DEJI DOHERTY LAWON KO NI I GBA

Egbe oselu PDP nipinle Eko, ti so o di mimo pe awon setan lati gba gomina ipinle Eko, Ogbeni Akinwunmi Ambode, sinu egbe awon to ba setan lati darapo mo awon. Ana, ojo Tosde, ni won kede oro yii sita.  

Ninu oro akowe ipolongo egbe PDP nipinle Eko, Ogbeni Taofeek Gani, lasiko to n ba awon oniroyin soro lo ti so pe ko si egbe oselu gidi kan ti yoo ri iru Ambode ti ko ni i gba sinu egbe won, a fi egbe ti ko ba fe ilosiwaju ati idagbasoke gidi lo ku, nitori pe oja gidi teeyan le kowole ni Ambode je.
Akowe ipolongo egbe PDP yii ni awon setan lati gba Ambode sinu egbe awon, ti okunrin naa ba setan lati darapo mo awon.
Sugbon Ojutole ri i gbo labenu ni pe awon oludije ipo gomina ninu egbe naa ni sa a idibo to koja, Ogbeni Jimi Agbaje ati Oloye Deji Doherty ti so pe aala lasan lohun ti akowe awon so yii, nitori pe awon mejeeji ti gba foomu lati dije ipo gomina ninu egbe PDP Eko. 



No comments:

Post a Comment

Adbox