A gbo pe ipade nla waye laarin gomina ati Senato Remi, eyi ti Senato Olamilekan Yayi ati Senator Barehu Asafa wa nibe. Alaye ti Senato Remi se fun Ambode ni pe gbogbo aye lo mo pe idagbasoke nla nijoba e ti mu ba ipinle Eko, Olorun yoo si fun un lokun ati agbara lati se ju bee lo to ba ti wole sipo gomina ni sa a keji to fee lo naa.
Pelu idunnu ati ayo ni won fi tuka leyin ipade yii. Fawon ti ko ti i gbo, wahala ti ki i se kekere lo n sele ninu egbe yii lori eni ti yoo dije ipo gomina nipinle Eko ninu egbe yii, awon meji mi-in, iyen Jide Sanwoolu ati Babajide Hamzat ni won ti gba foomu lati koju Ambode ninu egbe abele egbe APC.
No comments:
Post a Comment