IROYIN YAJOYAJO

ipolowo

Friday, 28 September 2018

GBAJUMO OLORIN EMIN, EFANJELIISI ROTIMI MICHAEL ONIMOLE(OBA ARA) KAWE GBOYE NILEEWE TI WON TI N KO NIPA ORIN

Gbajugbaja olorin emi omo orile-ede yii, Dokita Rotimi Michael Onimole ti gbogbo aye mo si Oba Ara ti gbe igbese akin lona orin emin to n ko. Ohun ti Ojutole gbo ni pe okunrin omo bibi Isale-Eko yii sese kawe gboye nileewe ti won ti n ko nipa orin, iyen 'Muson School of music'. Ni gbogbo asiko tawon olorin egbe e n wa owo kiri, imo nipa ise to so o dolokiki ni Oba Ara n wa ni tie.    
Oba Ara ti won sese fun lami-eye 'Grand Commander of Gospel Music' gba maaki to ga ju ninu imo to sese gba iwe eri e yii. Bakan naa la gbo pe iwe eri to sese gba nidii ise orin yii se deedee eni to kawe gboye iwe eri ti won n pe ni digiiri. .
Gbogbo awa osise ileese Ojutole naa ba Oba Ara dupe lowo Olorun fun igbese akin to gbe yii, Olorun yo je ko ri ere to po nidii e.

No comments:

Post a Comment

Adbox