Laipe yii lokan ninu awon agba-oje osere tiata ile wa, Bintu Fatimoh Ogunjimi, tawon eeyan mo si Oyeladun ninu fiimu segbeyawo alarinrin pelu okunrin ara Amerika kan toruko e n je Abdulrasheed Olansile Ijelu, omo bibi ikorodu. Bo tile je pe oko iyawo osingin ko si lori ijoko lojo naa, gbogbo awon ebi toko-taya yii ni won wa nibi ayeye igbeyawo ohun.
Yato sawon ebi iyawo ati ebi oko ti won wa nikale lojo yii, awon osere naa wa nibe, bee lawon ore Oyeladun ti won ki i se osere naa fi ojo naa ye e si.
Sugbon ohun to se awon kan ni kayeefi lori ayeye igbeyawo yii ni pe Oyeladun ko so fawon osere egbe atawon ore e kan pe oun gan-an loun lo sile oko, ohun to so fun won ni pe eeyan oun kan lo fee segbeyawo, ohun to so fawon oniroyin ti won wa nibe lojo naa niyen. Igba ti kaluku debe ni won too mo pe oun gan-an loun lo sile oko.
No comments:
Post a Comment