Taofik Afolabi
![]() |
Oga-Agba ajo HDI, Olufunso Wasanoye lo n da awon eeyan lekoo yii |
Lati je ki gbogbo awon omode ti ojo ori won si ye leni to ye
ko wa nileewe pada sileewe, ki eto eko si lo siwaju ju bo se wa y ii lo, ajo
kan ti ki I se tijoba to n ri si idagbasoke ati ilosiwaju awujo iyen ‘Human
Development Innitiatives’ ti sanilekoo fawon araalu atawon toro eko kan nipinle
Eko.

Lara awon ohun ti won sanilekoo fawon eeyan lojo naa ni, anfaani
to wa ninu ofin tijoba se pe gbogbo omo gbodo kawe ‘UBE Act’ todun 2004, ona tijoba
fi nawo lori e, ipa to ye kawon toro kan ko ati ijiya to ye ko wa fun eni to ba
tapa sofin yii. Bakan naa ni won tun da awon eeyan lekoo lori ona tawon toro
eko kan gbodo gba lati ri I pe gbogbo
awon omo pata ni won lo sileewe.
Lasiko to n senidalekoo fawon eeyan lojo naa, okan ninu awon
osise ajo HDI, Ogbeni Johnson Ibidapo, salaye lekunrere ohun ti ofin so nipa
ileewe alakobere. Ninu oro e lo ti so pe eko nikan lo le je ki eeyan wa nibamu
pelu awon ohun to n sele lagbaaye.O ni labe bo ti wu ko ri gbogbo eeyan lo nilo
lati kawe, o kere tan iwe girama ipele
alakoko.O ni, o se ni laanu pe ida ogota ninu ogorun-un awon eeyan ni won kawe
lorile-ede yii, bee lo buru jai pe orile-ede Naijiria lo gba ipo kin- in-ni ninu
awon orile-ede tawon eeyan won ko kawe daadaa.

Bakan naa lo salaye awon idi tawon omo ki i se lo sileewe, lara
e ni ise ati osi, fifi omo sise, komo tete lo sile-oko. O fi kun oro re pe aon omo
to ye ki won nileewe, sugbon ti won ko si nile-eko ni Naijiria je milionu mejila
ataabo.

O ni ojuse gbogbo awon eeyan lati fi to awon ti oro eko kan leti
nigbakigba ti won ba ri awon omode ti won rin regberegbe kiri igboro lasiko to
ba ye ki won wa nileewe tabi awon ti won gbe oja le lori nigba to ye ki won wa nile-eko,
ki won ma foju ko kan mi wo iru omo bee.
Yato si eyi, o ni kawon eeyan ri i pe won fi to awon ti oro
eko kan leti nigbakigba ti won ba ri awon ileewe ti won ko ni aga, tabili tabi
yara ikawe ti yoo mu eko rorun fawon omo.
![]() |
Ogbeni Johnson Ibidapo lon sedanilekoo fawon eeyan yii |
Iyaafin Wasanoye, te siwaju ninu oro re pe omo ti ko ba ni
eko ati imo jaguda niru omo bee maa n ya lojo iwaju. Bee lo so pe ileese ‘HDI’
seto eko ofe fawon omode ti won ko ni baba tabi awon ti obi won ti ku. O ni iru
awon omo yii gbodo wa nileewe ijoba, bee lo so pe awon tun lo maa n sedanilekoo
fawon omode nileewe won.
Bakan naa ni akowe igbimo to n ri si eto eko alakobere nipinle
Eko, ‘SUBEB’, Ogbeni Olatunde Anthony Adefuye naa ba wa soro, ninu oro okunrin
naa lo ti lu ajo ‘HDI’ logo enu fun ohun ti won se yii, o ni bo tile je pe
ijoba gbinyanju lati je ki eto eko muna doko,sugbon kudiekudie si wa ninu eto
eko. O ni ohun ti ajo HDI se yii fihan pe ki eto eko lo siwaju ki I se ohun
tijoba nikan le da se bi ko se ojuse gbogbo wa, ohun ti ajo HDI si n se lowo
niyen.
![]() |
Die lara awon eeyan ti won wa nibe niyii |
No comments:
Post a Comment