IROYIN YAJOYAJO

ipolowo

Saturday, 10 February 2018

Gbajumo akorin emi fo fi ilu London sebugbe, Segun Akinjagunla fee gbe orin 'Originality' jade

Taofik Afolabi

Okan pataki ninu awon omo orile-ede yii ti won se daadaa nidii ise orin niluu oyinbo ni Segun Akinjagunla. topo awon ololufe e mo si Oluomo. Opo rekoodu losere nla naa ti gbe jade, bee lo ti gba opolopo ami-eye nidii ise orin to yan laayo.

Iroyin ayo ti a mu wa fun yin lati odo osere naa ni pe o ti pari ise lori orin  kan to fee gbe jade to pe akole re ni 'Originality', eyi ti itumo reje 'Ojulowo.

Orin naa ti won sese pari ni Akinjagunla ti pa itu meje tode n pa ninu oko, orin to gbamuse, to ba igba mu pelu alujo ti ko lafiwe losere naa ko jo sinu orin yii bamubamu.

Lasiko to n ba wa soro, Akinjagunla ti awo e to gbe jade lodun to koja to pe akole re ni 'O se  Daddy Mi' si n ta lowo loja fi da wa loju pe awon ololufe oun ko ni i kabamo ti orin naa ba jade, nitori pe gbogbo won ni won mo  pe oun ki i je opolo dipo toun yoo je eyi ti ko leyin.

O waa ro gbogbo awon ololufe e pe ki won tewo gba orin oun yii to ba ti jade bi won se sawon toun ti gbe jade tele.     

No comments:

Post a Comment

Adbox