Taofik Afolabi
Okan ninu awon odo to sese n goke agba bo nidii tiata Yoruba ni Sade, eka awon to n saralesoo lomobinrin naa wa, tawon to mo on daadaa sapejuwe bii olopolo pipe to mo ise e nise daadaa.
Sugbon inu idaamu nla ati irora ti ko legbe lomobinrin naa wa nitori ijamba moto to sele si i, won si n wa iranlowo owo fun un gidigidi losibitu 'UCH' Ibadan to wa bayii.
Gege bi a se gbo, oko ere kan lomobinrin naa ti n bo niluu Eko lojo to nijamba moto yii, ti kinni ohun si po debii pe osere naa ko le dide duro di bi a n se soro yii.
Ninu oro gbajumo osere ile wa, Rasak Olayiwola tawon eeyan mo si Ojopagogo to fi isele yii to wa leti lo ti soro bayii 'Sade n ku lo o, ki o ma ba a ku, ka ma ba a pedin, e je ka fi ohunkohun ti a ba ni ran an lowo, eni mimo opolopo wa ni. Sade je okan ninu onigbinyanju, ojo ola e dara, eni naa to n goke agba nibi ise ere itage ni Sade je, to si n lakaaka lati laluyo. Eka asaraloge lo yan laayo nidi ise ere ori itage, enu ise naa lo si ti n dari bo lati ilu Eko ko too nijamba moto. Iru eleyii ko ni i sele senikookan wa o
UCH ni Sade wa lati Osu keje, odun to koja, gbogbo wa la si mo pe oro ibi ti a n wi yii, owo ni, igba ti apa kun ebi, ara, ni Folashade fi ke gbajare pe kawon eeyan ran oun lowo.'
Enikeni to ba fee ran Sade lowo, ko fi ohun to ba fee fun un sowo si i sinu akanti to wa lara foto e yii.
No comments:
Post a Comment