Taofik Afolabi
Ojo nla ti oga-agba ileese Radio Lagos ati Eko FM, Arabinrin Ayobami Sotonwa, awon looko-looko ati gbogbo awon osise ileese naa ko le gbagbe boro lonii, ti i se ojo ketala, osu keji, odun 2018, ti akowe- agba ati oga- agba ileese naa tele, Ogbeni Lekan Ogunbanwo, sabewo si won. Pelu idunnu ati ayo ni won fi gbalejo oga- agba tele yii. Arabinrin Sotonwa ati oga agba leka kara-kata, Alaaji Kayode Adumadeyin, ni won saaju awon osise yooku gba Ogunbawo lalejo

Ninu oro akowe agba tele naa, lo ti gboriyin fun awon ti won sakoso ileese Radio Lagos ati Eko FM bayii, o ni ipo ti oun ba ileese naa dun mo oun ninu koja aaye ati pe iroyin won ti oun gbo nita foun lokan bale ise rere ti oun se lasiko toun wa nipo oga-agba n lo siwaju si i lojoojumo.

Ninu oro e, Arabinrin Sotonwa, dupe lowo alejo pataki yii, o ni abewo ti won se yii foun lokan bale pe won ko gbagbe awon ise ti won ti se lasiko ti won wa nipo oga-agba ileese naa.

No comments:
Post a Comment