,
Ose to koja yii ni Oba Olanrewaju Ilemobade Ikuyemiku, iyen oba Oto Awori, nipinle Eko sayeye ojoobi odun metadinlogota, ti gbogbo awon oloye atawon omo ilu si ba baba naa dupe lowo Olorun.
Lsiko ayeye ojoobi ohun loba alaye naa ti be gomina ipinle Eko, Ogbeni Akinwumi Ambode lati tubo ranti agbegbe Oto-Awori nipa fi fun won lona to lo geerege ati ina monamona.
Oba Olanrewaju to je oba eleekerindinlogun lori ite awon baba nla re so pe laarin odun mewaa to ti wa lori ite awon baba re, niluu ni ina monamona, imototo laarin ilu ati beebee lo ko si mehe.
O tun ro awon omo oodua lati gbe esin isese laruge ju esin musulumi ati esin igbagbo lo nitori pe esin ajeji lawon esin yii.

No comments:
Post a Comment