IROYIN YAJOYAJO

ipolowo

Monday, 5 February 2018

'Ayeye Gbaareniyi Day' yoo milu titi, se iwo ti ra ankara tire bi?

Bi ojo se n sunmo lariwo ayeye  'Gbaareniyi Day' n gbale-gboko, papapaa niluu Eko ti won yoo ti se e, tawon omoYoruba tooto ti won n bo nibi ayeye naa ti n ra ankara ti won yoo fi wole sibe.
Bakan naa lawon eleto n sakitiyan lati ri i pe ojo nla ohun ye gbogbo omo Yoruba patapata. Laipe yii lawon eleto sabewo si Aare Ona-kaka-n-fo, Aare Gani Adams nile e to wa ni Omole,ti oloye nla naa si ti fi won lokan bale pe ojo naa yoo larinrin, yoo si je ojo ti gbogbo omo Yoruba ko ni i gbagbe boro.   
   Eye nla ohun ti won pe akole re ni ‘GBAARENIYI DAY’ ni yoo way lojo Eti, Fraide, ojo ketalelogun, osu keji, odun ti a wa yii, ninu gbongan 'Blueroof', to wa ninu ogba ileese telifisan  LTV8 l'Agidingbi, Ikeja, ilu Eko.



 
Gbajugbaja akorin fuji ni,  King Saidi Osupa Akorede Okunola,  ni yoo forin gidi da awon eeyan lara ya lojo naa. Aago mejila osan ni won bere iforowalenuwo fawon eeyan lenu lori kapeeti, nigba ti eto gangan yoo bere laago meji osan.
Aso ankara pelu iwe ipe lawon eeyan yoo fi wole sibi ayeye nla, tiru e ko sele nile Yoruba ri.
Fun alaye lekunrere lori ankara tabi o fee kopa ninu ayeye yii, pe awon nomba yii: 
08185207166
08023092382
08023218373
08033766552

No comments:

Post a Comment

Adbox