
Oba awon onifuji nile yii, Alaaji Abass Akande ti gbogbo aye mo si Obesere tabi Oga-Agba awon olorin yoo forin aladun da awon ololufe e lara ya niluu England. Ojo Eti, Fraide, ojo ketalelogun osu yii lere nla ohun waye ni Unity 12, Thomas Road, Industrial Estate, E-14 7BA. Lati aago mejo ale daaro ojo keji lere naa yoo fi waye
Lasiko to n soro nipa ere faaji naa, Obesere tawon mi-in tun mo si Ologbojo so pe gbogbo awon ololufe oun ni won yoo gbadun ori gidi ati alujo ti ko legbe lowo oun lojo yii. O ni ki gbogbo won jade wa lati waa gbadun ara won pelu orin ati ilu to je eti ni gbese.
No comments:
Post a Comment