IROYIN YAJOYAJO

ipolowo

Monday, 5 February 2018

Meka ni won ti fun mi loruko ti mo n je, Asiiri to wa ninu rekoodu mi akoko ree- Alariya Dublin


Okan ninu awon olorin ti won n se daadaa loke-okun ni Alaaja Rodiyat Ayinke Adeboye tawon eeyan mo si Hello Olohun. O daju pe nibikibi ati lojokojo ti won n ba daruko awon akorin gidi, paapaa orin esin, won ko ni i rin jina ti won yoo fi daruko osere  nla to je iyawo manija Pasuma, Mattew Ajiboye ti wo n pe ni ididowo si i.

Rekoodu meta lobinrin naa ti gbe jade, ti eleekerin n bo lona bayii, bee lo ti gba opo ami-eye nile yii ati loke-okun.

Laipe yii lo ba Taofik Afolabi, soro nipa irin-ajo e de idi orin, awon ohun to ti se atawon nnkan mi-in ti ko so fun akoroyin kan ri laye.    

Die ninu ohun to ba wa so ree

 Ojutole: E salaye die nipa yin fun wa

Alariya Dublin: Oruko mi Alaaja Rodiya Ayinke Adeboye tawon eeyan mo si  Hello Olohun, akorin islaamu ni mi.Ilu Igbono, nipinle Oyo ni won ti mi sinu ebi  Alaai ati Alaaja Sanni

Ojutole:Bawo le se bere ise orin?
Alariya Dublin:  Lati igba ti mo ti wa nileewe girama ni mo ti n korin, emi ni mo maa korin fun won ninu egbe awon akekoo ti won je musulumi ti won n pe ni MSS.

Ojutole: Ki lawon obi yin so, nigba ti e bere orin?

Alariya Dublin:  Ki n ma paro fun yin, baba mi ko fe ki n korin rara, sugbon mama mi fowo si i ni ti won. Sugbon nigba ti mo fee gbe rekoodu mi akoko jade ni won too fife han si i, awon ni alaga lojo ti a ko awo naa jade.  

Ojutole: Odun wo gan-an le bere si i ni mu orin bii ise? 
 
Alariya Dublin: Odun  2008, odun naa ni mo gbe rekoodu mi akoko jade, inu osu kefa la a sefilole e. 'Hello Olohun' la so oruko awo naa.

Ojutole:  Ki le ri ti e fi so rekoodu naa ni 'Hello Olohun'?
Alariya Dublin: Lati fi ko awon eeyan pe ki won sunmo Olorun,ki won ma fi irun wakati marun-un sere. 
Ojutole: Awon ileewe wo le lo?

Alariya Dublin: Mo lo sileewe 'Christ Church Cathedral School, Lagos Island fun ileewe alakobere mi, mo si lo si  'Falomo High School, Ikoyi Lagos, beeni mo lo si 'Secretarial School of typing and short hand' ki too lo si Kwara Poly.

Ojutole:  Bawo loruko Alariya Dublin’ ti e n je se waye?

Alariya Dublin: Ilu Meka ni won ti fun mi loruko yen, awon ololufe mi kan ni won fun mi.Ohun ti won so ni pe mo ma n pa eeyan lerin-in pupo.

Ojutole: Bawo le se dero  Dublin?

Alariya Dublin:  Okunrin kan toruko re n je  Twins 77, lo ba mi gba fisa orile-ede  Germany, leyin ti mo lo odun meji nibe, ni mo wole si  Dublin

Ojutole: Bawo ni iriri yin ni  Germany?

Alariya Dublin: Olorun mi o, ko derun rara, mo koko ko ede won ki too le sise nibe. 

Ojutole: Bawo nise orin ni  Dublin?

Alariya Dublin:Mo dupe fun Olorun

Ojutole: Iyato wo lo wa ninu ise orin ni Naijiria ati Dublin?

Alariya Dublin:Ko jo ara won rara,owo ti a fi mu orin yato si tiluu oyinbo. Fun apeere ti mo ba fee gbe rekoodu jade mo gbodo wa si Naijiria ki n too se e.  


Ojutole: Rekoodu meloo le ti gbe jade?

Alariya Dublin:  Mo ti se meta, ikerin lo n bo lona. Mo se 'Hello Olohun, Islamic News, I love Muhammad and Allahu ni'

Ojutole: E wo le feran ju ninu awon rekoodu yin? 

Alariya Dublin:  Ti a o ba ni i paaro, gbogbo e ni mo feran?

Ojutole: Ise mi-in wo le n se yato sise orin?

Alariya Dublin: Mo n sise noosi.

Ojutole:Igba wo ni ka maa reti rekoodu yin tuntun?

Alariya Dublin: Lagbara Olorun yoo jade ninu osu kesan-an odun yii.

Ojutole: Iru eeyan wo ni Alariya Dublin?


Alariya Dublin: Eeyan jeeje ni mi, mo loyaya, mo beru Olorun, mo si tera mo esin mi.

Ojutole:Ki le fee so fawon ololufe yin?



Alariya Dublin ati oko e, Mattew Ajiboye
Alariya Dublin:  Mo dupe lowo won, mo n fi akoko yii so fun won pe mo mo riri won laye mi, ki won ma fi Olorun sile nigba kankan. Mo feran gbogbo won denudenu.

No comments:

Post a Comment

Adbox