IROYIN YAJOYAJO

ipolowo

Saturday, 24 February 2018

Gongo so lojo ti Lola Ajibola, onitiata, sayeye ojoobi odun mejidinlogun fomo e, Adebukola

Taofik Afolabi
 
Ojo nla ti gbajumo osere tiata Yoruba nni, Lola Ajibola tawon eeyan mo si Queen Lollly, ko ni i gbagbe boro lojo Aiku,Sannde, ojo kejidinogun, osu yii, ojo naa losere to rewa daadaa yii to gbe fiimu 'Ounje Ale' jade sayeye ojoobi odun mejidinlogun fomo e, Adebukola Ayinde Adenuga. 
 
Ayeye yii to waye nile igbafe 'Pubbles  Hotel', Imodi Imosan, Ijebu-Ode, lawon eeyan pataki lawujo, latori awon onitiata,awon oloselu atawon omo jayejaye ti ba Lola ati omo sayeye ohun.
Lati aago meji osan  titi dojo keji layeye yii fi waye, bawon eeyan se jeun , ni won n mu, tinu omo olojoobi ati iya e naa n dun pe ojo naa soju fawon.

Fawon ti ko ba ranti, okan pataki ninu awon oserebinrin ti won loruko daadaa nidii ere ori itage ni Lola, o ti gbe opolopo fiimu jade, bee lo ti gba ami-eye ti ko lo n ka. 









No comments:

Post a Comment

Adbox