IROYIN YAJOYAJO

ipolowo

Saturday, 17 February 2018

Gongo so lojo ti gbajumo osere fuji nni, Atawewe gbami-eye ni soosi INRI

Taofik Afolabi




Lara ojo tawon omo ijo 'INRI Evangelical Spiritual Church' to wa ni Oke-Afa labe ojise Olorun nni, Primate Babatunde Elijah Ayodele ko ni i gbagbe boro lojo kerinla,osu keji odun yii ti iranse Olorun naa sayeye ojoobi e.

Ohun to je ki ojo naa dun daadaa ni ami-eye ti wo fi da gbajumo ati ilu mo on ka osere fuji nni, Alaaji Sulaimon Adio Atawewe tawon mi-in tun mo si Etu Fuji tabi Baba Oloye lola. Bi osere nla yii se wo inu ogba soosi INRI lariwo nla ti so, tawon eeyan n pariwo, 'Wewe Alaaji,

Etu o si oba o je', won pariwo yii titi ti Atawewe ti omo sese bimo lorile-ede Amerika fi jokoo lojo naa. Saaju ki won too gbe awoodu fun Atawewe lojo naa lawon eeyan to wa nibe ti n so pe awon fe ko korin fawon,ohun to se fun won lojo naa niyen.

  Sugbon Atawewe se ohun to jo awon eeyan loju pupo, dipo ko ko orin fuji tawon eeyan ti ro pe yoo ko lojo naa, orin emi lo ko fun won fun odidi iseju mewaa, eyi to je kayeefi fun gbogbo awon eeyan to wa nibe. Ohun kan ti gbogbo won tenumo ni pe awon ko mo Atawewe mo orin emi ko beeyen.

Ninu oro gbajumo akorin fuji yii lo ti gbosuba fun Primate Ayodele lori bo se n ran awon to ku die kaato fun ninu ijo e lowo. O ni ti gbogbo awon ojise Olorun ba n se ohun ti iranse Olorun yii se, ise ati osi yoo dinku lawujo. Bee lo so pe ami-eye ti won foun yii jo oun loju pupo, nitori pe oun ko ni I lokan pe won yoo foun lami-eye ni soosi,pelu bo se je pe musulumi ododo, to tun lo si Meka loun,ati pe oun ko ri ibi ti won ti ran eeyan lo si Meka ninu soosi ri.
O waa dupe lowo Primate Ayodele fun ami-eye to fun oun yi.i . Ninu oro Aare egbe awon ololufe ere boolu lorile-ede yii, Dokita Rafiu Ladiipo to gbe ami-eye ohun fun Atawewe lo ti so pe pelu ohun ti osere naa se fihan pe akorin to to gbangba sun loye ni, o loun ko mo pe olorin fuji le ko orin emi ko dun beeyen,la i fi okan pe meji. O fi da Atawewe loju lojo naa pe egbe oun setan lati ni ajosepo gidi pelu e, nitori pe awon feran olopolo pipe eeyan lodo awon  

No comments:

Post a Comment

Adbox