IROYIN YAJOYAJO

ipolowo

Wednesday, 7 February 2018

Agba-oje sorosoro, Kabieesi Owuro la wa yoo sayeye ojoobi e lara oto

Taofik Afolabi
Ilu Eko yoo mi titi lojo kerin, osu karun-un, odun yii, ti agba-oje sorosoro ori redio ati telifisan nni, Oloye Abdulkabir Adeyinka Olatayo Adewoye tawon eeyan mo si Kabieesi Owuro la wa yoo sayeye ojoobi ogota odun to dele aye.

Awon gbajumo olorin fuji nni, Alaaji Abass Akande Obesere, Adewale Ayuba ati Alaaji Sule Alao Malaika ni won yoo korin lojo naa.

Yato sayeye ojoobi yii, Kabieesi Owuro la wa to je  oloye nla nilu Esie, nipinle Kwara yoo tun fi ojo naa fun awon ti won kose sorosoro nileese e, iyen 'Ade World Communication' niwe eri, bee ni yoo tun sefilole ileese nla kan to  da sile lati segbelaruge orin fuji.

Awon eeyan pataki lawujo ni won n reti nibi ayeye naa. Gbogbo bi ojo naa yoo se ri le o ma ba pade lodo wa ni Ojutole




No comments:

Post a Comment

Adbox