Gbogbo eto lo ti pari lori rekoodu tuntun ti gbajugbaja akorin waka nni, Alaaja Amudalat Aweni Bello tawon eeyan tun mo si Aweni Oniwaka fee ko jade.
Awo tuntun naa to pe akole re ni 'Waka Rebranded' ni won yoo fi lole ninu gbongan 'Multi-Purpose Hall' to wa ninu ogba ileeese Radio Lagos-Eko FM lopopona Alhaji Lateef Jakande, Agidingbi, Ikeja.
Ojo kokanla osu keji odun ti a wa yii nikojade ati ifilole awo orin nla yii ti ilu mo on ka osere fuji nni, Alaaji Saidi Osupa Akorede Okunla yoo ti forin aladun ati ilu gidi da awon eeyan lara ya.
Lasiko to n ba wa soro nipa ayeye nla yii, Aweni Oniwaka to je oniwaka kan soso tijoba ipinle Eko yan gege bii asoju won fi da wa loju pe ojo naa yoo larinrin, gbogbo awon ololufe oun pata ni won yoo gbadun ara won daadaa lojo yii.
Aweni to so orin waka di ohun tawon alakowe atawon osise ijoba n jo bayii ro gbogbo awon ololufe e pata lati fi ojo naa ye oun si,nitori pe ti ko ba si awon,ko si oun naa. Awon eeyan pataki lawujo atawon olola ni won reti nibi ifilole yii.

No comments:
Post a Comment