IROYIN YAJOYAJO

ipolowo

Sunday, 28 January 2018

MURI THUNDER FOGBA YANGA: EMI GAN-AN NI MR FUJI

Okan ninu pataki ninu awon osere fuji to loruko daadaa lorile-ede yii ni gbajugbaja osere Fuji nni, Alhaji Muri Alabi Thunder Orimadegun. Osere omo bibi ilu Ibadan yii kuro ni onifuji tawon eeyan yoo maa juwe ki won too mo pe oun ni, oodu ni laarin awon elegbe e ki i saimo foloko.


Laipe yii ni Olootu magasinni Iroyin Ojutole, Taofik Afolabi, sabewe sakorin fuji nla yii tawon eeyan tun mo si Mr Fuji tabi Muri The Genius yii.

Lasiko iforowero yii lo ti so pe leyin ti Oloogbe Sikiru Ayinde Barrister ti won n pe ni Mr. Fuji ti jade laye, oun ni ipo naa to si bayii. O ni gege bii Aremo Fuji ti Barrister  foun je nigba aye e, sugbon ti baba naa ti ku, ko selomi-in toye Mr Fuji to si to ju oun lo, nitori pe ti Oba ba ti ku, Aremo lo ye nipo, ko si si ohun to tun gbodo da aremo duro lati gun ori ite baba re, ohun to fa a niyen toun fi di Mr Fuji bayii,ti gbogbo ase orin naa si ti wa lowo oun.

Bakan naa ni Muri tun salaye awon nnkan mi-in nipa e ti ko salaye fun oniroyin kan ri laye lojo ti a sabewo sii yii.Die ninu ohun to ba wa so ree.


  OJUTOLE: Oro kan to n lo nigboro bayii lagboole fuji loro Mr. Fuji ti e je laipe yii, ki lo fa oye yii?

Muri Thunder: Mi o ro pe o ye ko ba awon eeyan lojiji rara, nitori pe gbogbo aye lo mo pe igba ti baba mi, Oloogbe Sikiru Ayinde Barrister wa laye ni won fi mi je Aremo Fuji, ohun to han si gbogbo aye ni. Awon eeyan ti won feran orin fuji ni won so fun mi pe awon ko fe ki oruko yen ku, won ni gege bi Aremo Mr. Fuji ko selomi-in tipo naa to si ju emi lo.  Mo si fee fi asiko yii so fun gbogbo awon ololufe mi pe a o je ki gbogbo aye mo nipa ohun ti a se yii, se e mo pe oro yii dabii eni to joba ni, awon kan yoo fara mo on, awon kan ko si ni i gba, sugbon ohun to je ki oro yii lojutuu ni pe funra baba ni won fenu ara won so pe emi ni Aremo awon, nigba ti won si ti lo sibi tagba n re yii, ki Aremo bo sori ite baba e lo ku. A si maa sajoyo e kaakiri.

Lara  igbese ti a gbe lati je ki gbogbo aye mo pe emi ni Mr. Fuji bayii ni rekoodu wa kan to n bo lona,  ti a pe akole e ni Mr. Fuji, ka too ri ose meloo kan si i yoo jade. Ninu e ni mo ti salaye daadaa bi oro oye naa se je. Ileese Dam Jay Records lo fee gbe e jade, oun naa ni yoo ba wa pin in fun gbogbo awon to n ta rekoodu.  Koda awon ojise Olorun bii Aafaa Muhedeen Bello ti fowo si i, won ti fi onte lu u, baba wa Alaafin Oyo naa ti fowo si i, awon ti ko faramo ni won mo ohun ti won ri nigba ti eni to ni nnkan ti so pe emi ni  oun fe,  sugbon gege bi Mr. Fuji, mi o gbodo ba awon ti won binu yii binu rara, eni to ba wa nipo nla beeyen gbodo ni suuru daadaa.

Ohun ti mo ko sinu rekoodu yii po, ninu e ni mo ti korin bayii 'Emi Muri, Mista Fuji lo n pede yii, Muri, Mr Fuji lo n lo ohun lowolowo, sebi Barry lo fi mi je Aremo, nigba ti Barry si wa laye, ko too di pe Barry papo da oo, o ni nitori pe toun ba papoda o, lowo yii ti Barry ti waa papoda o, emi ni Mr. Fuji isinyi, emi ni Mr Fuji, se e ri Mr Fuji ti mo je yii, mi o je lati ri awon agbaagba fin oo'. E je ka fi i sile beeyen, nnkan ki sese rago loro rekoodu yen, awon temi si mo mi lojokojo pe mi o ni ja won kule laelae.        

  OJUTOLE: Se e ko ro pe oye ti e je yii ko ni i bi Alaaji Wasiu Ayinde ti won je oba fuji ninu, abi e ti gbase lowo won ke e too maa je oruko yii?

Muri Thunder: Asaaju mi ni won, baba ni won je fun mi, ajosepo gidi lo wa laarin wa. Awon naa ti mo bi gbogbo e se n lo, okiki oruko yin ti kan de odo won, o si da mi loju pe won ko ni i binu, nitori pe awon naa mo pe emi ni kinni ohun to si.

  OJUTOLE: Laipe le sokuu mama yin, tawon osere fuji meji tawon eeyan mo pe ota ni won, iyen Alaaji Wasiu Alabi Pasuma ati Alaaji Saheed Osupa naa wa nibe. Bawo le se se e ti e fi ri awon mejeeji ko wa sibe?

Muri Thunder: Olorun lo se e, ki i se awon ti e daruko yen nikan ni ko rorun lati ri, gbogbo awon osere fuji ti won wa nibe ni ko rorun lati ri. Emi naa maa n lo sode won, mi o koyan won kere, eeyan daadaa lawon mejeeji.

  OJUTOLE: Yato si oye Mr. Fuji ti e je yii, awon nnkan mi-in wo lo n sele si Muri Thunder bayii?

Muri Thunder: Opo nnkan ni mo n se lowo, kaluku lo mo ohun to n fi owo e se, ise orin yii naa ni mo n na owo mi le lori. A  n ko ileewe orin tawon odo ti won lebun orin yoo ti maa waa kekoo nipa orin nibe, a da ajo alaaanu kan sile lati fi ran awon eeyan lowo, a da iko agbaboolu sile, a fee se yara ti won ti n ka orin sile, tawon olorin yoo ti maa ka orin won sile. Mo wo o pe ileese to ni i se pelu ariya ni mo gbodo ko owo mi le lori, ti mo ba da ileese ti won ti n se omi sile, awon ti mo gba sibe ni woôn yoo je e run, nigba ti n ko mo nnkan kan nipa e, sugbon ise orin yii, ko si ohun ti won le fi ru mi loju ninu e.

  OJUTOLE: Laipe yii lakobi yin kawe jade nileewe giga yunifasiti, bawo lo se ri lara yin?

Muri Thunder: Ope naa ni mo n da, nitori lara aseyori mi ni pe omo mi kawe jade ni yunifasiti, lara ojo tinu mi dun ju laye niyen.


No comments:

Post a Comment

Adbox