IROYIN YAJOYAJO

ipolowo

Friday, 26 January 2018

Won fee seye nla fun Aare Ona-kaka-n-fo l'Ekoo,Ayajo Gbaareniyi ni won pe e,King Saidi Osupa ni yoo korin



 Lati owo Taofik Afolabi
Gbogbo eto lo ti pari bayii lori eye nla ti won fee se fun Aare Ona Kaka-n-fo tuntun, Aare Ganiyu Abiodun Adams.
Eye nla ohun ti won pe akole re ni ‘GBAARENIYI DAY’ ni yoo way lojo Eti, Fraide, ojo ketalelogun, osu keji, odun ti a wa yii, ninu gbongan 'Blueroof', to wa ninu ogba ileese telifisan  LTV8 l'Agidingbi, Ikeja, ilu Eko.


 
Gbajugbaja akorin fuji ni,  King Saidi Osupa Akorede Okunola,  ni yoo forin gidi da awon eeyan lara ya lojo naa. Aago mejila osan ni won bere iforowalenuwo fawon eeyan lenu lori kapeeti, nigba ti eto gangan yoo bere laago meji osan.

Aso ankara pelu iwe ipe lawon eeyan yoo fi wole sibi ayeye nla, tiru e ko sele nile Yoruba ri.
Fun alaye lekunrere lori ankara tabi o fee kopa ninu ayeye yii, pe awon nomba yii: 
08185207166
08023092382
08023218373
08033766552

No comments:

Post a Comment

Adbox