Gbajumo akorin omo orile-ede yii to fi ilu Ireland sebugbe ni Anjola Leo Bravo, okunrin naa ki i se eeyan kekere nidi ise orin rara. Bayii osere nla ti won fi joye oba orin juju ni Ireland ti so o di mimo pe agba-oje olorin juju nni, Sir Shina Peters lawokose oun lenu ise orin.
Lasiko to n ba akoroyin wa soro, Bravo ni ' Lati kekere ni mo ti n gbo orin baba wa Sir Shina Peters, awon lawokose mi nidii ise orin, orin won kan ti won pe ni 'Ace' to gba gbogbo ilu kan nigba kan la wa n wo nigba naa, ohun to fi wa lokan bale pe awa naa yoo saseyori nidii ise orin yii, a si dupe lowo Olorun pe o gbe wa soke nidii ise naa.
Arewa okunrin yii waa fokan gbogbo awon ololufe e bale pe awo oun tuntun n bo lona,nibi tawon eeyan yoo ti gbo orin aladun ati alujo to ki popo.
Nice One
ReplyDelete