Iroyin to te wa lowo bayii ni pe oko gbajumo osere tiata ile wa, Opeyemi Ayeola,iyen, Babatunde Mattew Owolomonse ti yonda e lati pada sidii ise tiata to so obinrin naa di ilu mon on ka laarin awon elegbe e.

Gege bi a se gbo, laipe lokunrin to fi ilu London sebugbe yii pe iyawo jokoo, to je ko mo pe oun ti fi tokantokan fara mo on pe ko pada sidii tiata. Pelu idunnu ati ayo ni Opeyemi fi kede nnkan ayo ti oko e so fun un yii, ko si fakoko sofo rara to fi loo kede e lori ero ayelujara bayii pe ' Olasexcy mi, mi o bi mo se le salaye ohun ti o se yii, iwo lo dara ju laarin awon okunrin lagbaaye.
Emi funra mi mo pe ona kan soso ti mo fi le ni igbugbe ayo ati ebi gidi ni pe ki n fi ise mi sile lati mojuto awon omo ati oko mi, mo dupe lowo re fun iranlowo ti o se fun mi lati tunbo lo ebun ti Olorun fun mi, loooto iwo ni angeeli ti Olorun ran si mi, ojulowo ade laarin gbogbo ade. Mo feran e daadaa Olayiwola Abdulwakil Babatunde temi ni kan.
Gbogbo eyin ololufe mi nile ati leyin odi, te n beere pe ibo ni Opeyemi Ayeola wa, mo ti pada wa bayii pelu iranlowo oko mi, ayaba ti de, o ya e ba mi dupe, e ba mi yo.'
E o ranti pe odun 2007 ni Opeyemi ati Babatunde segbeyawo alarinrin l'Ekoo, leyin ayeye igbeyawo naa ni Ope gba ilu London ti oko e n gbe lo, latigba naa ko ti kopa ninu awon fiimu to n jade mo. Sugbon bayii, ti oko e ti gba fun un lati pada sidii tiata, a je pe awon eeyan yoo tunbo gbadun Ope bayii.
No comments:
Post a Comment