Pelu ekun kikoro ati omije loju ni won fi sinkuu okan ninu awon omo eyin gbajumo akorin emi to filuu Ibadan segbugbe, Ajiyinrere Bukola Akinnade tawon eeyan mo si Senwele Jesu, iyen Shina Afolabi to faye sile lojo meloo kan seyin.

Se lawon eeyan sunkun kikoro nigba ti won fee gbe okunrin naa wo kaa ile lo, se lawon ti ko le mu kinni ohun mora bu sigbe, ti ko si eni to le re enikan dake ekun.
Leyin ti Shina lulu tan leyin oga e nibi eto kan to waye nile ijosin Lion of Judah to wa niluu Ibadan laisan ohun deede ki i mole,ti won si sare gbe e lo sile iwosan ijoba UCH, sugbon lojo naa ni elemi-in gba a .
Awon to mo okunrin yii sapejuwe e bii eeyan jeejee, to feran ise,to si ko awon eeyan mora.
A gbadura pe ki Olorun te e safefe ire,ko si tu awon ebi e loju.
No comments:
Post a Comment