Taofik Afolabi
Ajalu nla kan lo sele lagbo awon osere wa, okan ninu awon to n ya fiimu ti won n pe ni camera man, iyen Ademola Ariyo lo ku, leyin aisan kindinrin to ko lu u.
Saaju ki okunrin to ya fiimu, Osuofia in London, Blood money, Igodo, Goje Africa lokunrin kan toruko e n je Olanrewaju Malcolm, ti pariwo sita pe kawon eeyan dide iranlowo si i lori aisan to n se yii, sugbon won ko ri milionu mejila naira ti won fee fi toju okunrin ayaworan naa tolojo fi de.
Nibi ti wahala ati idaamu yii po de, seni Ariyo maa n toro owo ati ounje lowo awon araadugbo e ni Surulere, nibi to ti n toro owo yii lolojo ti de ba a lanaa. Awon osise eto ilera nipinle Eko, ni won pale oku e mo, ti won gbe e lo si monsuari.

K'Olorun te e si safefe ire.
No comments:
Post a Comment