IROYIN YAJOYAJO

ipolowo

Wednesday, 31 January 2018

Nitori ami-eye repete to gba, Mega 99 dupe lowo awon ololufe

Ilu mo on ka akorin,to tun je oludasile orin gospel-juju, Omooba Abel Dosunmu tawon eeyan tun mo si Mega 99 ti dupe lowo awon ololufe e fun ami-eye repete ti won ti da a lore nidii ise to yan laayo.

Osere nla omo bibi ilu Ilaro,nipinle Ogun yii dupe lowo gbogbo awon ololufe e fun ife ti won ni si i ati bi won se duro ti oun latigba toun ti bere ise orin.
Mega 99 tawon ololufe e tun n e ni Oluwajekayemo so pe ti ko ba si awon ololufe oun,ko si eni ti won yoo maa pe ni Mega 99 nitori pe ola Olorun ati ola won lo n sako.

    Lara awon ami-eye ti Mega 99 ti gba ni

 Akorin emi to mo awon eeyan da laraya ju lo latowo Ooni Ife Royal Award

Akorin juju to dara ju fodun 2017 latowo ileese City People Magazine

Akorin Juju to dara ju fodun 2017 latowo ajo YOMAFA

Akorin juju okunrin to dara ju latowo ileese Kapers Int.

Ami-eye idalola latowo ijo  CCC Ikorodu 1 Cathedral

Ami-eye idalola latowo awon akekoo ilu Yewa.
Olorin ti won n gbo orin re ju latowo ileese 'Roll-world Magazine'

Ami-eye idanilola latowo ajo Glorious Youth Organization

Ami-eye idanilola latowo egbe akorin Makoko

 Ami-eye idanilola latowo 'The Glorious Youth Ijegun, Ijebu Ode, ipinle Ogun
Akorin emi to dara ju latowo 'Miracle Heaven Parish, Ibafo
Ami-eye idanilola latowo ijo C.C.C Olorunda Parish Akobo, Ibadan.

No comments:

Post a Comment

Adbox