IROYIN YAJOYAJO

ipolowo

Wednesday, 31 January 2018

ISE IYANU REE O: ARA WERE YA NIBI TAWON AKORIN IJO TI N SEDANRAWO

Taofik Afolabi


Gbogbo awon eeyan ti won gbo nipa omobinrin were kan to gba iwosan ni won so pe ise iyanu kan ree o. Aago mefa irole ana nisele nla yii waye nile ijosin Ridiimu 'City of David' to wa ni nitosi oja Ita Ale,niluu Ijebu -Oru,nipinle Ogun. i Temitope Lateef Adunni ni won pe oruko obinrin naa.

 Gege bi a se gbo, lasiko tawon akorin ijo yii n se idanrawo ninu ile ijosin yii ni were yii bere si ni i jo si orin ti won n ko, to je pe bi  won se n korin, lo kijo mole, tinu oun naa si n dun.

Asiko yii ni adari egbe akorin so pe oun gbo ohun kan to wi foun pe kawon gbadura fun obinrin naa, sugbon oun ko ti eti ikun si ohun ti oun ba oun soro yii nitori pe ita ile ijosin naa ni were naa ti n jo.

Nibi ti won ti korin yii ni were yii ti waa ba won ninu ile ijosin naa, to tun n kijo mole burukuburuku, asiko naa ni gbogbo awon omo ijo yii bere adura isegun fun obinrin naa. Ninu adura yii lara re ti ya, toju re wale,won koko fun un lounje, ko too di pe won ge irun e fun un, ti won si fun un laso tuntun.

Leyin ti won gerun fun un tan ni won mo pe olomoge, bee lobinrin so oruko re ati ibi to ti wa fawon ara ijo yii.
Kinni kan tawon eeyan n so ni pe ise iyanu nla leleyii o. 


No comments:

Post a Comment

Adbox