IROYIN YAJOYAJO

ipolowo

Monday, 29 January 2018

Ayeye ojoobi ogoji odun:Kayode Salako soro iwuri nipa iyawo e,Foluke Daramola


Bi ayeye ojoobi ogoji odun  gbajumo osere tiata Yoruba nni, Foluke Daramola Salako se n sunmo, oko e, Olukayode Salako,  to je oludasile ileewe giga Bosworth College International NG to wa nilu Osodi ti soro iwuri nipa osere nla naa.

Taofik Afolabi


Ninu oro okunrin naa lo ti so bayii pe ' Mo n gbe igbe ayo pelu obinrin to feran mi denudenu, obinrin to mu igbe aye rorun fun mi,obinrin ti ko mu wahala ati a i bale okan wo ile aye mi.

Ore mi ni, alatileyin mi ni, afadurajagun mi ni, woolii mi, eegun iha mi to dara ju. Opo igba lo ti bori idanwo ati ijakule to n be ninu ife, o ti fi han mi pe ife otito lo ni si mi. Ojo keeedogun, osu keji, odun yii ni waa pe omo ogoji odun laye. Mo ki e ku oriire, eni okan mi,  Foluke Omolola Daramola Salako.

Loooto ati lododo, obinrin  rere ni o, akoni , akinkanju oloriire laarin awon obinrin yooku. ko si iye ola, ipo, imo, itiju, tabi ohunkohun laye yii ti ko ni i je ki n maa polongo re gege bii oloriire ati obinrin rere.

Ku imurasile ayeye ojoobi e, Ibadiaran mi. Emi ni  oko re too ti ko legbe, Olukayode Salako

No comments:

Post a Comment

Adbox