IROYIN YAJOYAJO

ipolowo

Wednesday 13 March 2024

O ye ki ijọba orileede ede yii gboriyin fun awọn ọdọ, nitori awọn ni ọjọ ọla Naijiria--Oluṣọ Ọladele Genesis





Agbọlade Toyin
Oludasilẹ ijọ Genesis Global to fidi kalẹ kaakiri igboro ipinlẹ Eko,Oluṣọ Ọladele Ogundipẹ Genesis ti sọrọ lọsẹ to kọja nipa awọn ọdọ ,o sọ pe awọn ni ogo ọjọ ọla orile ede yii ti yoo si dara ti awọn ijọba ba le maa gbe oriyin ki wọn si maa ki wọn lẹyin ti wọn ba n gbe ohun rere ṣe ni ilu abinibi wọn nipa ṣiṣe eyi awọn ọdọ ko ni i gbero lati lọ maa ṣiṣẹ idọti ni orilẹ ede miiran
Oluṣọ Genesis sọrọ yii lasiko ti ijọba ipinlẹ Eko paṣẹ pe ki makẹta awọn olorin takasufe nni iyẹn ọgbẹni Abu Abel kuro lori ilẹ olowo nla kan to ṣẹṣẹ ra si agbegbe Ọlọgọlọ nitosi Etiosa Lẹkki nipinlẹ Eko,o sọ pe lẹyin ti ọmọ bibi Rẹmọ nipinlẹ Ogun ti gba awọn iwe to yẹ to dẹ ti sanwo tan ni awọn kan sọ pe,aṣẹ wa latodọ AarẹTinubu pe Ṣeyi ọmọ Aarẹ lo ni ilẹ naa ti ọgbẹni Tayọ Ayinde naa si mọ nipa ẹ.
Genesis wa sọ pe,oun mọ pe Aarẹ to fẹran awọn ọdọ ni Aarẹ Orilẹ ede yii bẹẹni ọgbẹni Ṣeyi to ololufẹ awọn ọdọ naa ki n ta ọrọ awọn ọdọ nu,o wa sọ pe ki wọn fi pẹlẹpẹlẹ yanju ọrọ yii nitori ọgbẹni Abu ti n jiya bọ lati ọjọ pipẹ,ti iwa yii si le jẹ ki ọpọ ọdọ maa sa lati wa gbe ohun rere ṣe ni orilẹ ede wọn,oluṣọ ti wa sọ pe ki ọgbẹni Tayọ Ayinde maṣe jẹ ki ọrọ ilẹ yii di ija laarin awọn ọdọ nitori olufẹ ọdọlangba ni Ayinde fun ra ẹ,bẹẹ lo sọ pe o dara kawọn ọdọ maa gbeja ara wọn nitori agbajọ ọwọ la fi n sọya

No comments:

Post a Comment

Adbox