IROYIN YAJOYAJO

ipolowo

Friday 22 September 2023

Oga awon Onisegun ibile, Dokita Akintunde Ayeni Yemkem ni: Idile oloogun ponbele ni won ti mi-Ojo meje ni baba to bi baba mi fi po oogun nigba to fee ku




 

 

Oriṣa oke jẹ n da bii onile yii, ki loju onile ti ri ko too kọle nla ki i ye ọpọ eeyan. B’olowo ba sọ ohun toju rẹ ri ko too dẹni aye n sa tọ, talaka mi-in yoo ni koun ṣaa ti maa r’ọbẹ jẹkọ lasan ti daa.

Ọmọwe Akintunde Ishọla Ayẹni, Alaṣẹ ati Oludari ileeṣẹ YEMKEM International, ti wọn n ṣe oogun  iwosan ibilẹ, eni ti gbogbo eeyan tun mọ si Pathfinder lorilẹ-ede yii ati kaakiri agbaye, lo pe ọgọta ọdun laye,(60 years). N ni ẹgbẹ akọroyin ledee Yoruba, League Of Yoruba Media Practitioners (LYMP)  ba ni ko sọ iriri rẹ latọdun to ti n ba kinni ọhun bọ faye, nigba naa lọkunrin ọmọ wọn niluu Ọyẹ Ekiti naa bẹrẹ alaye nipa bo ṣe jiya, ati bo ṣe jẹ pe ọmọde mọkanla ko ba tọwọ oun ku lọjọ kan ṣoṣo, atawọn nnkan mi-in. Akintunde ṣalye, o ni:

 

’’ Ṣe ẹ ri, ninu gbogbo nnkan laye yii, ka tiẹ kọkọ dupẹ lọwọ Eledumare ni, nitori pẹlu Oluwa, Ohun gbogbo ni ṣiṣe.

 Mo dupẹ pe mo wa laye, mo wa laaye. Ki i ṣe irin -ajo to rọrun, irinajo to ni oriṣiiriṣii koto ati gegele ni, to kun fun eruku oriṣiiriṣii, ṣugbọn mo dupẹ f’Oluwa pe Ọlọrun da mi si titi dasiko yii, nitori ọpọlọpọ ojo lo ti rọ tilẹ ti fa mu.

Ọpọlọpọ la jọ ṣe kekere lati ọmọ ọjọ kan ti wọn o si mọ lonii, ọpọlọpọ la jọ ṣe kekere to jẹ aaye t’Ọlọrun fi mi si, awọn o si nibẹ. Ki i ṣe pe mo gbọn tabi pe mo mọ ọn ṣe, bi ko ṣe pe mo ri aanu Ọlọrun ọba gba ni.

Irinajo to le gan-an ni mo rin, bi mo ṣe maa n sọ fawọn ọmọ mi gan-an pe ọpọlọpọ wọn ko le mọ ohun ti mo la kọja afi ti mo ba sọ ọ, ti mo ba waa n sọ awọn iriri mi fun wọn, o maa n jẹ iṣoro fun wọn lati ti gba a gbọ, wọn aa ni ‘Daddy, ṣe ootọ dẹ loun tẹ n sọ yii?’.  Idi ni pe awọn o lo iru igbesi aye yẹn, iyẹn maa n jẹ ko ṣoro fun wọn lati gbagbọ.

Nigba ti mo maa de Eko yii, ọdọ ẹgbọn mi ni mo de si.

Ọgbọn ọjọ (30 Days) ni mo lo nibẹ to fi kẹru jade, to fi mi silẹ sinuu yara yẹn, o de ko gbogbo ẹru ẹ pata kuro ninu ile.  Mo wa sun ninu ile yẹn fun ọgbọn ọjọ mi-in, ni Kiateka ba le mi jade nigba ti mi o rowo san.

Ile yẹn, Opopona Ṣadare lo wa, ni Muṣin.

Nigba ti Kiateka le mi jade yẹn, ẹgbọn mi to ko lọ si adugbo mi-in sọ pe mi o le tẹle oun lọ sibẹ, mo wa bẹrẹ si i sun kaakiri, ko too di pe mo waa ba iya kan to gbajumọ daadaa niluu Eko yii pade, mama yẹn n gbe n’Ikẹja, wọn ni aisan aromọleegun, mo maa n lọọ tọjuu wọn.

 

Mama yẹn lo wa ba mi ṣe ọna ti mo fi rile kan si Ṣomolu (Mo ti n ṣiṣẹ iṣegun lati 1981), ṣugbọn 1982 lawọn eeyan bẹrẹ si i mọ mi daadaa. Mo pari ileewe girama mi ni 1980.

 

Lẹyin ọdun kan ni mo lọọ kawe si i, mo tun waa lọọ ṣe kọọsi ọlọdun meji mi-in ni Maiduguri, ẹkọ nipa imọ nipa ẹja sinsin ni mo kọ ni Maiduguri, nilẹ Hausa. Ile Hausa ni mo ti kọkọ bẹrẹ si i ṣiṣẹ, ni Kano ati Maiduguri, ti mo n fun awọn eeyan loogun.

Ṣugbọn nilẹẹ Yoruba, Akurẹ ni mo ti bẹrẹ si i fun awọn eeyan loogun, iyẹn ni 1981. 1982 ni mo de Kano ati Maiduguri. Ẹ wo o, irin ajo mi ri bakan o, owo ti mo ba ri nidii iṣẹ iṣegun ni mo fi tọ ara mi jade fọdun meji.

1986 ni mo d’Ekoo, 1987 ni mo dẹni to gbale, igba ti mo gbale ni 1987 yẹn, ẹgbọn mi to le mi jade nile pada waa gbe lọdọ mi fọdun kan atoṣu mẹfa, itan to gun gan an ni.

 Mama ti mo ni mo pade lo ni oun ko fẹ ki n gbe ni Muṣin, o ni ‘Ẹ mu-un-ṣin-in’  ni wọn n pe ni Muṣin.

O lawọn kọstọma mi ko ni i fẹẹ maa wa mi wa si Muṣin o, nitori adugbo to le ni. Mama yẹn lo ba mi wale si Ṣomolu ni 1987 yẹn. Àṣé emi ni ẹni kẹrinlelogun (24) to sanwo  yara kan ṣoṣo naa ,emi o dẹ mọ nnkan kan. Lanlọọdu ti gbowo lọwọ mi, Atanda lorukọ ẹ, ti mo ba debẹ, aa ni ki n wa lonii, ki n wa lọla, o ṣaa n daamu mi ni.

Mama n beere lọwọ mi pe risiiti owo ile ti mo san nkọ, mo ni wọn o fun mi ni risiiti, lo ba ni ‘haa, Eko ẹ ree, wọn ti lu ẹ ni jibiti’.

Mo ni mama, ki ni ma a ṣe? Ogoji naira lowo yara naa loṣu kan. Mama sọ fun mi pe maa lọọ da a bii ọgbọn ni o, o ni ki n lọ sinu ile yẹn, ki n sọ fun wọn pe lanlọọdu wọn ti lu jibiti, ki n sọ fun wọn pe oloogun ni mi o, pe mo n bọ waa da Ṣanpọnna sinu ile yẹn.

Emi naa ba gbera  nitootọ, mo mu ado kan dani lọwọ irọlẹ ti gbogbo wọn ti maa wa ninu ile, ni mo ba debẹ, mo ki wọn kaalẹ, mo ni mo ro pe gbogbo yin ti maa n ri mi ninu ile yii ti mo n wa, wọn ni bẹẹ ni,awọn mọ mi.

 

Mo ni ẹni bayii-bayii ni mi o, Ekiti ni mo ti wa o, lanlọọdu yin gbowo ile lọwọ mi ko fun mi nile. Ohun ti mo kan waa sọ ni pe owo yẹn, ki i ṣ’emi ni mo ni in, awọn agba awo l’Ekiti lo dawo fun mi, wọn dẹ ti gbe oogun fun mi bayii, Ṣanpọnna, pe ki n waa fi sinu ile yii.

 Ni mo ba mu ado yẹn jade, mo fi han wọn, ni wọn ba pariwo pe haa, ki n ma da a sinu ile o. Wọn ni ki n maa bọ laaarọ ọjọ keji, pe ma a ba owo mi nilẹ. Ni mo ba lọ laaarọ ọjọ keji loootọ, mo ba a nile, wọn o jẹ ko jade. Aago mẹrin lo maa n ji jade, nitori awọn to gbowo lọwọ wọn ti pọ.

Lo ba ni mo fẹẹ tu ile mọ oun lori, mo ni mi o tule mọ ẹ lori, owo to o gba ni ko fun mi pada. Lo ba fa mi wọle, lo ba ni ọmọ Ekiti naa lẹni to wa ninu yara yẹn, aafaa dẹ ni, (mi o ni i darukọ ẹni yẹn).

O loun ati aafaa yii wa ni kootu lorii yara yẹn, ṣe ẹyin naa ri i. Yara t’ẹjọ wa lori ẹ to o dẹ lọọ n gbowo ibẹ.

O ṣaa pada fi mi mọ ẹni ti wọn jọ n fa ọrọ yara yẹn, niṣe lo nawọ ile ẹni naa si mi lọọkan. O gba mi loṣu mẹta lati ri ẹni yẹn kiyẹn too gba lati gbe ẹjọ naa kuro ni kootu. Aafaa lẹni yẹn loootọ, ṣugbọn o jẹ ki n mọ pe oun ko fi bẹẹ mọ oogun, emi wa bẹrẹ si i kọ ọ loogun, nigba to tiẹ ti jẹ pe ọmọ ilu kan naa ni wa, o si pada loun o ṣẹjọ mọ.

Nigba to gbe ẹjọ kuro ni kootu tan, ọjọ to fẹẹ mu kọkọrọ yara naa silẹ, emi o tete dele, lanlọọdu yẹn ti gba kọkọrọ lọwọ ẹ ki n too de. Mo ṣaa beere pe bawo wa tun ni, emi ni mo ṣaa jẹ ki wọn gbe ẹjọ kuro ni kootu, lo ba ni oun o le file naa rẹnti mọ, afi ti mo ba sanwo ọdun meji mi-in si i. Mo ni lati sanwo ọdun meji mi-in ni kile yẹn too bọ si mi lọwọ.

Gbogbo asiko irin ajo yẹn, ẹgbọn mi yẹn ti ni iṣoro nibi to ti n ṣiṣẹ, bo ṣe pada waa gbe lọdọ mi niyẹn. itan to gun gan-an ni o, nigba ti ẹgbọn mi tun de ọdọ mi, o ni firiiji, tẹlifiṣan atawọn ọpọ nnkan bẹẹ yẹn, emi o dẹ ni nnkan kan, gbogbo ẹru yẹn lo ko wa sinuu yara ti mo gba.

Oun ati lanlọọdu mi tun waa di i, pe risiiti toun kọ fun mi yẹn, pe k’ẹgbọn wa ọna ko lọọ ji i, pe oun maa waa kọ risiiti mi lorukọ ẹgbọn mi, oun aa sọ pe ẹgbọn mi lo gbale lọwọ oun, ki i ṣe emi.

Ṣugbọn nigba t’Ọlọrun maa ṣe e, emi o si nile, mo lọ si Kano, nitori Kano ni mo ni kọstọma to pọ si. Awọn mẹta ni wọn jọ ditẹ yẹn, ẹnikẹta wọn ni Ọlọrun lo fun mi, iyẹn dẹ mọ ibi ti mo tọjuu risiiti yẹn si ninu yara, iyẹn lo waa lọ mu risiiti naa to lọọ tọju ẹ. Risiiti yẹn ni wọn wa titi  ti mo fi de, bi gbogbo imọ yẹn bo ṣe daru niyẹn.

Itan to gun gan-an ni o, ni 1987 yẹn naa ni baba mi ku, ni mo ba tun bẹrẹ si i gbiyanju laye, awọn aburo wa lẹyin mi lati maa tọ wọn. Gẹgẹ bi mo ṣe sọ pe ilẹ Hausa ni kọstọma mi pọ si, awọn eeyan diẹdie ni mo kan maa n ri l’Ekoo nibi,  ṣugbọn ọdun t’Ọlọrun fẹẹ tan irawọ mi jade gan-an ni 1989.

Mo wa nile, ọrẹ mi kan ta a n pe ni Thumos Speretu, oun lo waa ba mi nile to loun gbọ pe wọn fẹẹ ṣe International Trade Fair ni Badagry, pe ki n waa lọọ ṣoju ipinlẹ Ondo, (Ko ti i si ipinlẹ Ekiti nigba yẹn). Bi mo ṣe lọ niyẹn. Emi nikan ni oniṣegun ibilẹ lati ipinlẹ Ondo nibẹ, ileeṣẹ tẹlifiṣan meji naa lo dẹ wa sibẹ nigba yẹn, awọn naa ni NTA Tẹjuoṣo ati LWTV.

Wọn maa waa n ka ohun ta a ba n ṣe silẹ, wọn aa fọrọ wa wa lẹnu wo, ‘Alaafia tayọ la n pe eto wa nigba yẹn. Igba ta a pari International Trade fair yẹn, ti mo pada sile, awọn eeyan bẹrẹ si i wa kaakiri niluu Eko.

Ọdun to tun tẹle e ti i ṣe 1990, mo tun lọ. 1991 ni, ọrẹ mi kan, Adeyinka, a jọ lọ sileewe naa ni, oun n gbe ni Yaba. Oun lo wa ni Ayẹni, o da bii pe wọn fẹẹ ṣe ipatẹ iṣegun ni Tẹjuoṣo o. Emi o gbọ ọ ri, o ni wọn maa n polowo ẹ lorii tẹlifiṣan, emi o tiẹ ni tẹlifiṣan, ko jẹ ki n mọ. O waa gbowo lọwọ mi, o lọọ gba fọọmu, o ṣe gbogbo ẹ.

Wọn pari International Trade Fair lọjọọ Sannde, wọn bẹrẹ ipatẹ iṣegun lọjọọ Mọnde. La ba ko gbogbo eru wa lọ sibẹ. Ọpọ eeyan lo wa si International Trade Fair lati ri mi, ṣugbọn wọn o raye ri mi, nitori ero ti pọju. Awọn eeyan ti wa nita to jẹ pe kawọn kọstọma too wọnu ile wa, wọn aa ti ra ohun ti wọn ba fẹẹ ra nita.

Nigba ti mo maa de Tẹjuoṣo, ni ti 1989, gbogbo owo ta a kọkọ pa nibẹ jẹ ẹgbẹrun lọna ogoji naira (40,000) Mo fowo yẹn sanwo awọn to n ba mi ṣiṣẹ, awọn to n polongo fun mi ati bẹẹ bẹẹ lọ.

Ṣugbọn 1991 ti mo lọ si Tẹjuoṣo, ti wọn ni ka bẹrẹ si i ta ọja, gbogbo wa ko ju isọ mẹrinlelogun lọ (24 exhibitors) Emi gba isọ kẹrindinlogun, Alaaji Ajaṣẹ Pokipoki (K’Ọlọrun fọrun kẹ wọn), awọn gba isọ kẹẹẹdogun, Dokita Salvage, Awiṣẹ ilu Eko lo maa n gba isọ kin-in-ni.

Nigba ti awọn Babaniji to jẹ olori awọn onifidio to n rikọọdu wa de ọdọ mi, wọn bi mi pe ṣe mo maa rikọọdu, mo ni ma a rikọọdu, elo dẹ ni nigba naa, Faifu ọndirẹdi naira (500) ni iṣẹju marun-un, ni mo ba sanwo, ni wọn ba rikọọdu mi.

Ni mo ba ni too, gbogbo oju to n wo mi nile o, Alaafia tayọ, gbogbo ẹyin tẹ ẹ ti lọ si International Trade fair tẹ ẹ o raye ri mi, mo ti wa ninu ọgba Tẹjuoṣo ni NTA Channel 7, ẹ maa bọ.

Ẹ wo o, ọjọ keji, ẹni ti o le rin ni ki wọn gbe oun niṣoo nibẹ. Emi o dẹ mọ, emi o riru ero bẹẹ yẹn ri laye mi. Mo wa nile, mo ṣi n sun gan-an laaarọ, ṣugbọn awọn bọisi kan n ba mi ṣiṣẹ, awọn bii Yọmi, Gani, Aafaa. Nigba tawọn ọmọ yẹn maa de sitandi mi laaarọ, ero ti bo ibẹ  , bi wọn ṣe waa ba mi nile niyẹn, pe ọga, ẹ dide o, ẹro ti wa ni ‘Stand’.

Bi mo ṣe dide niyẹn, mi o wẹ, mo kan fọnu ni, ni mo ba káṣọ sọrun, kia mo ti de Ọdunlade Bus-stop, mi o ni mọto o, mo gbe Danfo, o di Yaba, lati Yaba, o di Tẹjuoṣo.

Mo bẹrẹ si i da awọn eeyan lohun laago mọkanla aarọ, mo pari ẹ laago mejila oru. Nibi ti ogun ti bẹrẹ niyẹn, tawọn eeyan n kọ haa, nibo lọmọ eleyii ti wa? Kinni kan, kinni kan.

O tun di lọjọ keji, ipolowo kan ti mo ṣe yẹn, wọn ni  ṣe ka wọn tun lo o, mo ni ki wọn lo o. Ida mẹsan-an awọn eeyan ti mo n da lohun lasiko naa sọ fun mi pe awọn ti wa mi lọ si Trade Fair. Alaafia tayọ ọlọpaa aṣẹ ni wọn maa n pe mi nigba yẹn, nitori mo ni nnkan to jẹ pe ti mo ba ti gbe e le wọn lọwọ bayii, ma a maa wo gbogbo bi igbesi aye wọn ṣe n lọ patapata ni, mo maa ri gbogbo ẹ. Ọta pọ o.

K’Ọlọrun ba mi fọrun kẹ ọga agba NTA nigba naa, Oloye Bọde Alalade, ipatẹ iṣegun nigba yẹn ki i kọja ọjọ meje, o pọ ju, ọsẹ meji.  Ṣugbọn lara awọn t’Ọlọrun ni ki wọn jẹ ọrẹ si mi, Ajaṣẹ Pokipoki, Alaaji Tajudeen Alalukimba (K’Ọlọrun ba mi fọrun kẹ wọn), ati Madam Ara-n-fẹ-aajo, awọn agba iṣegun nigba yẹn niyẹn, Ọlọrun ni ki wọn nifẹẹ mi, wọn ri i pe ọmọ kekere ni mi, ṣugbọn wọn ni ẹni t’Ọlọrun ba ti gba fun, ẹ gba fun un naa lo yẹ.

 Mi o le gbagbe ọrọ Tajudeen Alalukimba, o ni ẹni t’Ọlọrun ba ti fun ni, gidigba o ṣilẹkun, ẹni t’Ọlọrun ba fun ni kọkọrọ ẹ ni.

Nitori ọtẹ mi, awọn ẹbọ to to ẹbọ, ipese to to ipesẹ, wọn aa gbe e sẹnu ọna isọ mi, tawọn ọmọ mi ba de laaarọ, ẹbọ ni wọn maa ba nisọ mi. Awọn ẹbọ kankan ti i kagun laya, tawọn ọmọ yẹn ba ti ri i, ko kuku si foonu, wọn aa tun sare waa ba mi,  ‘Ọga, Tẹjuoṣo lawọn ti n bọ nisinyin o, ẹbọ bii marun-un ni wọn gbe siwaju standi wa o.

 Ma a ni ki wọn lọọ tọ sinu  ẹ, ki wọn tọ si i ki wọn si gbe ẹbọ naa danu, ero tun maa maa ya ni.

Ogun yẹn pọ debii pe awọn kan gbagbọ pe mo ti ri nnkan mọnu ọgba Tẹjuoṣo ni, ni wọn ba lọọ ba ọga agba pe ko ba wọn ṣewadii, pe nibo lọmọ kekere yii ti ri agbara to n lo.  

Emi o dẹ ni nnkan kan ju bi mo ṣe n lo agbara ti iṣẹ iroyin ni lọ, ‘Power of the Media’ lo ran mi lọwọ, awọn o dẹ mọ iru ẹ, oju wọn ko la si i.

Mo de tun wa ni nnkan ti wọn n pe loogun to n jẹ lọwọ, nitori ko si ipatẹ ta a maa lọ lọdun yii, ọdun to n bọ bayii, o maa lọpọ ẹ ni. Oloye Bọde Alalade to  jẹ ọga agba NTA Tẹjuoṣo nigba yẹn lo wa ni, Alaafia tayọ, ki i ṣe ipolowo ipatẹ iṣegun nikan ni wa a maa lo o, eto rẹ yii gbọdọ maa lọ bẹẹ ni o.

Bi mo ṣe bẹrẹ si i lo ọgbọn iṣẹju fun ipolongo lorii tẹlifiṣan niyẹn.

Igba ti mo bẹre yẹn, mo wa gbe e gba ọna mi-in, nitori awọn ida mẹsan-an awọn ti wọn n ṣeto lorii tẹlifiṣan nigba yẹn ti won  n polowo iṣegun, aafaa ni wọn, musulumi ni wọn.

Awọn tẹ ẹ maa maa ri lori tẹlifiṣan nigba yẹn ni awọn nii Abdul Jabar, awọn Ọkọ Oṣo-ọkọ ajẹ, Anjọọnu Ibẹru, awọn Falaki, Alalukimba, Alaaji Akeula ati bẹẹ bẹẹ lọ ti wọn n rọwọ mu.

Emi waa ro o pe bawo ni mo ṣe fẹẹ ṣe temi pẹlu eto ọgbọn iṣẹju yii, mo wa ni ma a gbe temi gba ọna ere ori itage. Mo waa pe eto mi ni Alaafia tayọ, nitori ko sohun to to Alaafia, mo waa gbe awọn Alaaji Ajilẹyẹ wọle (K’Ọlọrun fọrun kẹ wọn).

 Mo gbe wọn wọle lati maa fi ere ori itage polongo eto mi. Ti mo ba fẹẹ sọrọ nipa alakalaa,nigba yẹn to tiẹ jẹ ida mẹsan-an iṣẹ ti mo n ṣe da lori aye ni,  beeyan ọgọrun-un ba wọle waa ba mi nigba yẹn, aadọrun-un ninu wọn (90),isọro ni wọn gbe wa, ki i ṣe ilera.

Ti mo ba waa fẹẹ sọrọ nipa alakalaa, awọn Alaaji Yẹkini Ajilẹyẹ aa ṣere nipa bi ọmọ ẹda eeyan ṣe maa n lalaa, bi ala ṣe n wa loju oorun. Ogun iṣẹju ni wọn maa fi ṣe e, iṣẹju marun-un pere lemi maa fi sọrọ bi wọn ba ti fẹẹ pari ẹ.

Ẹ wo o, ko sibi ti wọn o ti mọ mi nigba ti mo n sọ yii, nitori ti wọn ba ti bẹrẹ eto yẹn ni NTA Tẹjuoṣo, gbogbo igboro Eko maa n da ni.

 Ko si foonu tawọn eeyan le maa wo bii tisinyi nigba yẹn, ileeṣẹ tẹlifiṣan meji naa lo wa ni gbogbo Eko yii, NTA Tẹjuoṣo ati LWTV, wọn o ti i sọ ọ di LTV 8 nigba yẹn.

Ti wọn ba ti bẹrẹ si i kọrin pe, ‘Alaafia tayọ o, alaafia lo ṣagba, alaafia lo ṣọga, mura sọrọ ara rẹ ooo, ko too kawọ sori.’  Ẹ wo o, onikaluku maa fohun to n ṣe silẹ ni, wọn n lọọ wo eto mi, eto yẹn fun mi lọpọ okiki.

Ti mo ba fẹẹ sọrọ nipa airọmọbi, a maa gbe e yẹwo, mo maa sọ itan fawọn Alaaji Ajilẹyẹ ni, awọn aa waa lọọ sọ ọ di ere. Fun apẹẹrẹ, a sọrọ nipa ohun to n fa airọmọbi, mo sọ awọn ohun to le jẹ idiwọ latọwọ Iṣẹda, mo tun sọ eyi tawọn aye naa n fa, ti wọn si ṣe e ni ti ere agbelewo.

Ẹ maa ri obinrin to wa nile ọkọ, to n fẹẹ ki ọlẹ ọmọ sọ ninu oun, asiko to yẹ ki nnkan oṣu sé lara ẹ lo maa bẹrẹ si i lalaa, lo maa ri i pe oun loyun loju oorun, oun bimọ, aa tun ṣekomọ yẹn loju oorun. Obinrin mi-in wa, to ba ti ku diẹ koyun duro si i lara bayii, o le jẹ nnkan pupa lo maa ri loju ala, to ba dijọ keji, ẹjẹ maa jade labẹ ẹ ni. Mo waa gbe kinni kan yẹwo lori eto, a pe e ni Tẹṣọọ.

Nigba ti wọn ṣafihan eto yẹn tan, lọjọ keji ẹ, awọn ọkunrin to yọju si mi pe Tẹṣọọ n ṣe awọn to ida mẹsan-an aabọ( 95 %). Ki dẹ ni Tẹṣọọ? Ẹlomi-in o mọ itumọ ẹ, Alaaji Ajilẹyẹ gan-an ko mọ ohun ti wọn n pe bẹẹ, sugbọn mo jẹ ko ye wọn, nitori ọsẹ mẹtala ta a fi n ṣeto, mo ti maa fun wọn ni akọle ohun ti wọn maa ṣẹ lọsẹ kọọkan, wọn maa wa kọ ọ nikọọkan bẹẹ, wọn aa sọ di ere agbelewo.

Mo waa sọ fun wọn pe itumọ Tẹṣọ ni pe tọkunrin ba niyawo meji, mẹta, to ba ti di pe to ba dọdọ ẹnikan, ara rẹ aa le, aa le ṣe. To ba dọdọ ẹnikeji ti ko le ṣe, tẹ ẹ ba tanna saarin ọrọ naa, Tẹṣọọ ni wọn fi ba a ja.        

Mo waa sọ itan yẹn fun wọn, awọn wa ṣe e lere, wọn ṣafihan ọkunrin to niyawo meji. Iyaale lọọ ṣoogun kan sinu abẹrẹ, tọkọ ba ti fẹẹ waa ba a, o maa fi abẹrẹ yẹn ha irun ori ẹ, bọkọ ba fọwọ kan an lasan, ara ọkọ aa le bii iṣan ni, aa le sunmọ daadaa.

Tọkọ ba tun ti kuro lọdọ ẹ, o maa lọ fi abẹrẹ yẹn ha ibi kan ninu yara ẹ, ki ọkunrin yẹn lọ sọdọ ọgọrun-un obinrin, ko ni i le ṣe nnkan kan. Iru ọkunrin bẹẹ yoo kan maa lo oogun ti oko rẹ yoo fi le ni, ofo ni, aa maa ni jẹdijẹdi ni, ko sohun ti wọn o ni i pe e tan, ko baa lo ọgọrun-un oogun, ko le mu un.

Ba a ṣe fi ṣe sinina bẹẹ yẹn tan, hmmm, lọjọ kan ṣoso, awọn ọkunrin to wa mi wa fun itọju ti mo dẹ da lohun jẹ ẹgbẹta (600).

Fun idi eyi, oriṣiiriṣii nnkan ni mo ti gbe yẹwo, ọpọlọpọ nnkan to ṣokunkun sawọn ẹda nile aye ni mo ti gbe jade. O ti le lọgbọn ọdun daadaa, nigba Alaafia tayọ. Ṣugbọn ṣe ẹ mọ, nigba tọjọ n lọ, ta a n wo o, a ri i pe ta o ba mura, ọjọ ọla iṣegun ibilẹ ko ni i jẹ itẹwọgba, nitori ọpọlọpọ awọn eeyan, enu abuku ti wọn fi maa n ba a ni pe oogun ibile ko ni packaging, ko nigba, ko lodinwo.

Emi nitemi, mo da pinnu ni, pe mo fẹẹ kọja si ipele to kan, iyẹn ni mo ṣe pinnu pe mo maa yi orukọ ẹ pada kuro ni Alaafia tayọ, ti mo sọ ọ di YEMKEM Internatational. Bi aarin ibẹ yẹn ṣe lọ niyẹn.

Nipa bi mo ṣe mọ agbara to wa ninu lilo iṣẹ awọn akọroyin ati ipolongo

Ti ẹ ba wo awọn baba wa laye ọjọun, wọn ti wa nidii iṣẹ yii fọdun rẹpẹtẹ. Meloo ninu wọn lo jokoo, ti wọn gbe kamẹra siwaju rẹ ri ti wọn si fọrọ wa a lẹnu wo? Ko si.

Wọn o naani wọn, wọn o ka awọn oniroyin kun, wọn o si mọ iṣẹ ti wọn n ṣe. Ohun to kọkọ mu abuku ba iṣegun ibilẹ laye yii niyẹn.

Ikeji, yatọ si pe emi kawe, mo dẹ jade, ṣe mo sọ pe International Trade Fair ni mo ti kọkọ gbera mi jade lawọn asiko ọdun 1980, a o tiẹ ti i wọ 1990 rara.

 Mi o tiẹ mọ pe awọn kan n bọ waa rikọọdu mi, mo ro pe awọn ti wọn ba waa ra oogun yoo kan ra a wọn yoo si maa lọ ni, ọjọ akọkọ ti mo maa mọ agbara ti tẹlifiṣan ni, awọn LWTV ni wọn wa, wọn o gbowo, wọn kan sọ fun mi pe, ’’Alaafia tayọ, Ondo State Pavillion, ni wọn ba ya awọn oogun ta a ko silẹ, ko tiẹ ti i si ‘packaging’ nigba yẹn, wọn kan ṣafihan ẹ lerefee lorii tẹlifiṣan ni pẹlu emi ni, ṣugbọn aa riṣẹ ohun ti wọn fi han yẹn lara ọja wa.

Nigba to tun di ọjọ keji, wọn tun waa rikọọdu, nigba ta a maa fi pari ta a pada sile, awọn to wa nigba ta a pada sile nkọ, aa ri i pe ohun to n jẹ bi idan ni. O kan jẹ pe iyẹn o lọ bẹẹ, a tun n duro de ọdun mi-in.

Ohun ti mo wa ṣe ni pe nitori mo ni awọn ọrẹ ta a jọ kawe ti wọn ti kawe ju mi lọ, mo ni awọn to wa nidii iṣẹ iroyin. Koda, ọkan ninu awọn to ju mi lọ nileewe nigba yẹn, wọn n pe e ni Emmanuel Osokwu, oun lo mu mi lọ si Daily Times, olootu wọn nigba yẹn ni Chinaka Finecountry.

Nibẹ ni wọn ti fun mi laaye ti mo fi n kọ nnkan sinuu beba naa nigba yẹn, laarin awọn ọdun 1980 naa ni. Iyẹn lo waa wo o pe kinni yii maa gbe iṣẹ mi larugẹ.

Ohun lo fa a to fi jẹ pe nigba ta a de Tẹjuoṣo-Yaba, isọ mẹrin lemi nikan sanwo  ẹ. Wọn ni iṣẹju marun-un fidio jẹ faifu ọndirẹdi naira, ni mo ba ko o le wọn lọwọ, wọn dẹ rikọọdu mi fun iṣẹju marun-un.

Bi wọn ṣe pari iroyin laago mẹwaa alẹ, wọn kan ṣa a si i ni. Igba yẹn dẹ ree, ina wa, o fẹ, o kọ, o gbọdọ wo NTA. Ida mẹjọ awọn to n gbe l’Ekoo nigba yẹn, NTA Channel 7 lo maa wo.

 Ọjọ keji bayii, ile mi da bii omi ni, fun ero. Ṣugbọn awọn mi-in ta a jọ n ṣiṣẹ yii, agbalagba ni wọn, emi nikan lọmọ kekere inu wọn. Omi-in aa sọ pe wọn o ti i bi iya ẹ toun ti n ṣoogun, nibo lo ti wa? nibo lo ti ri gbogbo awọn ero wọnyi?

O lagbara gan-an o, debii pe ni 1998, mo lọọ  ṣepade n’Ijẹṣatẹdo, wọn ni ero ti pọju lọdọ mi, wọn lawọn fẹẹ da ṣanpọnna sọdọ mi. Lara awọn ti wọn jọ ṣepade yẹn naa lo waa sọ fun mi, ibẹ ni mo ti bẹrẹ si i gba isọ mẹta papọ dipo ẹyọ kan.

Ma a gba 16 ati 17. Ẹni yẹn sọ fun mi pe awọn ero to maa n ṣujọ siwaju mi yẹn lo n bi wọn ninu, pe ki n jẹ kawọn ero yẹn maa wa ninu ile.

Oriṣiiriṣii ọrọ, isasi loriṣiiriṣii, ko sohun ti wọn ki i pe mi tan, wọn aa ni ọmọ yẹn, o da bii pe o ti gbe nnkan mi.

Nigba to wa ya ti ikunnsinu ati ifisun yii n pọ, ẹnikan ti wọn n pe ni Adetukasi ( oludari ẹka ipolowo ọja ni NTA Tẹjuoṣo ni),  oun lo waa pe wọn pe kawọn mẹrin da owo jọ, kawọn naa bẹrẹ si i ṣeto lọsọọsẹ, to ba tun di lọsẹ keji, o ni ki wọn tun dawo jọ kẹlomi-in tun ṣeto ninu wọn, awọn naa waa bẹrẹ si i ṣeto, wọn waa n ri iyatọ ninu ọja wọn. Nigba naa ni wọn ṣẹṣẹ waa mọ pe agbara ipolongo ni mo lo, oogun kọ.

Ṣe ẹ mọ, ọpọ awọn baba wa igba yẹn o lanfaani siru ẹ. Mi o ri baba mi kẹni kan pe e ri laye yii pe, ‘Baba, ẹ waa ṣalaye,’ titi to fi ku. Ka ni wọn ṣe e ni,o ṣee ṣe kiṣẹ iṣegun yii ti lọ ju bayii lọ kiru awa yii too de.

  Tẹ ẹ ba wo o, emi lẹni akọkọ ni Naijiria lonii to maa kọkọ fi oogun ibilẹ sinuu kapsu (Capsule).  Wọn o gbagbọ pe o le ṣẹlẹ, ṣugbọn ṣe ẹ mọ, bi emi ṣe ti ni iriri to, mo jade, awọn nnkan yẹn ran mi lọwọ. Mo lọ sawọn ilu kaakiri ti wọn ti n ṣe iṣegun ibilẹ, mo lọọ kọ bi wọn  ṣe n ṣe e ti wọn fi juwa lọ.

Tẹ ẹ ba wo China lonii, wọn ti bẹre iṣegun ibilẹ o ti lẹgbẹrun ọdun mẹrin, wọn ti ṣe akọsile rẹ. Ṣugbọn ootọ ibẹ ni pe ijọba China ran awọn iṣẹ ibilẹ wọn lọwọ.

Ni China lonii, tẹ ẹ ba ri ile ita-oogun mẹwaa, mẹjọ ninu ẹ, oogun ibilẹ wọn ni wọn n ta, ti wọn n lo.  Wọn nigbagbọ ninu oogun wọn ti i ṣe Chinese Traditional Medicine (CTM).

Boya awa naa fẹ tabi a kọ,alawọ dudu ni wa,oogun ilẹ wa lo yẹ ka gbe larugẹ. Oloogbe Ọjọgbọn Lambo sọ pe, aisan ilẹ adulawọ, oogun ilẹ adulawọ naa lo nilo ka lo si i .

Fun idi eyi, ohun ti mo ro pe a le fi gbe iṣẹ yii ga nigba yẹn naa ni ipolongo, ohun to le mu BBC, ni London, ti wọn wa sibi waa fọrọ wa mi lẹnu wo, Hillary Anderson lorukọ oyinbo to waa fọrọ wa mi lẹnu wo. Tunde Kelani, (TK, Mainframe), lo darii kamẹra lọjọ naa, 1998 lohun ti mo n sọ yii.

Ohun ti wọn dẹ ṣe ni pe wọn waa ṣe akojọpọ awọn nnkan ibilẹ wa fọjọ meje( Documentary).  Mo mu wọn lọ si ọja, ẹ wo o, ẹsin ti ko si wa lọpọlọ, ko jẹ ka mọ nnkan ta  a n ṣe ni. Oyinbo yẹn, Hillary Anderson lati BBC, o fẹẹ mọ ba a ṣe n ṣe oogun ibilẹ wa, bawo la ṣe n se asejẹ fun eeyan?

Ti wọn ba de oyun mọ obinrin ninu, bawo lawọn agba atijọ ṣe n ṣe e tobinrin yẹn aa bimọ? Tọmọ ba dubu sobinrin ninu, bawo ni wọn ṣe n ṣe e tọmọ yẹn aa yi pada?

Iyẹn ni mo ṣe mu wọn lọ sọja, mo lọọ fi awọn nnkan han wọn. Ijapa, Okete, Ẹyẹ Igun,oriṣiiriṣii awọn nnkan abami to wa lọja, ọja Ojuwoye ni mo mu wọn lọ.

Iya mo-in, nigba ti wọn n ṣafihan akojọpọ kinni naa lorii tẹlifiṣan, ọmọ rẹ to wa niluu oyinbo lo ri i to sọ fun un pe oun ri i lorii tẹlifiṣan.

Igba ti wọn ṣafihan rẹ ni BBC, awọn CNN naa gba a lọwọ wọn, wọn waa ran John Ken si mi, lati CNN, pe koun naa waa ṣe akojọpọ tiẹ. Gbogbo ẹ wa nile itọju nnkan si awọn BBC titi donii. A dupẹ f’Oluwa, tẹ ẹ ba wo bawọn BBC ṣe ya fidio naa nigba yẹn, o wuuyan lori pupọ.

Bi mo ṣe n wẹ, ihooho mi nikan ni wọn  o gbe, bi mo ṣe n mura, bi mo ṣe n jẹun, bi mo ṣe n jade, bi mo ṣe n wọle, gbogbo ẹ ni wọn gbe, nitori wọn mọ iyi awọn nnkan iṣẹdalẹ wa ati oogun ibilẹ wa.

Iyen lo fa a ta a fi ro o pe o yẹ ka ṣe igbelarugẹ awọn oogun wa, nnkan ti mo ronu nipa ẹ ni, tori ẹ lo fi jẹ pe jijade mi lati gbe iṣegun ibilẹ larugẹ lo fun gbogbo oniṣegun ni Naijiria lonii lanfaani lati jade, ki wọn maa gbe e larugẹ, nitori ẹ ni wọn ṣe n pe mi ni ‘Pathfinder’, Olulana, nitori emi ni mo bẹrẹ ẹ.

A dupẹ f’Oluwa, ko sẹni to mọ pe iṣegun ibilẹ le de ibi to de yii.

Complex tẹ ẹ wa yii, nigba ti mo n kọ ọ ni 2001, ọdun mejilogun sẹyin, awọn eeyan o gbagbọ pe oniṣegun ibilẹ kan le kọ iru  ẹ, wọn n sọ pe ẹni yii ṣoogun owo ni o, nigba to ya wọn ni kokeeni ni mo n gbe.

Bẹẹ, ile mi akọkọ l’Ekoo yii, ọdun 1995 ni mo kọ ọ, awọn Cararra Marble lo waa ṣe gbogbo marble inu ile yẹn. Owo ti mo fi kọ ile yẹn din diẹ ni milọnu lọna ogun ni, ni 1995.  Owo mi to wa wa ninu ẹ ti mo le sọ pe owo temi gangan ni, mi o ro pe o to miliọnu kan. Awọn eeyan lo fun mi, mo ti ni kọstọma to pọ.

K’Ọlọrun ba mi fọrun kẹ baba to ni Cararra Marble, wọn n pe e ni Oloye Ajiṣọmọ Alabi ( Lord Dumex). Baba isalẹ mi ni wọn. Baba naa wo mi lorii tẹlifiṣan ni, ni 1990.

 Baba naa waa ba mi, wọn ni ṣe emi ni mo n sọrọ lorii tẹlifiṣan, awọn wo eto mi, mo ni emi ni baba. Wọn ni emi kọ ni mo n sọrọ, awọn baba mi to wa lọrun ni. Wọn ni emi ni mo n pa itu meje yẹn, mo ni emi ni. Baba ti mo n sọ yii, ile ti mo ni mo kọ yẹn, ki n tiẹ sọ pe baba yii ko fun mi lowo rara, aa fun mi ni wan miliọnu to ẹẹmẹta.

Ikeji, gbogbo marble ti wọn fi ṣe ile yẹn pata, awọn Cararra marble ni wọn waa ṣe e. Ọjọ ta a n ṣile yii, awọn eeyan ni niṣe ni mo ṣoogun owo, ile ti mo n gbe tẹlẹ ti onile n sọrọ pe ero ti n pọju to n wa mi wa, pe mo fẹẹ gba ile lọwọ oun ni.

Ṣe ẹ mọ, ibukun latọdọ Ọlọrun wa leyi. A bẹrẹ iṣẹ yii lasiko to wa lẹyin-rere. Eeyan meloo lo tẹwọ gba oogun ibilẹ nigba yẹn, ki lo de fa a, ọna ti wọn n gba a ṣe e ni, ọna to luko. Oun lemi ṣe jade lọ sawọn orilẹ-ede kan, ti mo lọọ wo bi wọn ṣe n ṣe tiwọn, idagbasoke yẹn lemi naa waa gbe wọle.

Ọjọ ti awọn NAFDAC kọkọ fun mi laṣẹ lori oogun mi, Arabinrin Dora Akunyili ko ti i de nigba yẹn, asiko ijọba ologun ni, NAFDAC wa ṣugbọn wọn o ti i gbilẹ to bayii, bi wọn ṣe waa fun mi laṣẹ ati maa ta oogun yẹn, mo waa wo o pe ki n ṣe e si kapsu, mo waa lọọ sọrọ lori ẹ ni NTA Tẹjuoṣo.

Ọjọ keji, lati ileeṣẹ eto ilera, wọn kan ilẹkun ile mi pe ki n ṣalaye bi mo ṣe le ṣe oogun ibilẹ sinuu kapsu, wọn ni ko ṣee ṣe, mo dẹ fi gbogbo ẹ han pe o ṣee  ṣe. Mo gbe maṣinni jade, mo gbe agunmu jade, mo rọọ sinu kapsu lojuu wọn nibẹ, wọn n lanu silẹ ni, mo dẹ jẹ ko ye wọn pe bi wọn ṣe n ṣe e niluu oyinbo niyẹn, ko si nnkan to wa nibẹ, imọ ẹrọ lasan ni.

Nitori tẹ ẹ ba wo o, ọpọ eeyan ni Naijiria nibi, oogun to ba koro, wọn aa lawọn o le lo o, pupọ oogun ibilẹ lo dẹ koro, tawọn baba wa ba gbe agunmu wa, wọn aa ni ka maa fi ẹkọ gbigbona lo o, beeyan fun ọmọ kan niru ẹ nisinyi ko ni i lo o, o maa da a nu ni, wọn ti gbagbe pe ohun to ba koro ni ọrẹ inu.

Ṣugbọn aa dupẹ pe nigba ta a waa ṣe e si ọna igbalode, iyatọ wa. Nitori ẹ ni mo ṣe gboriyin fun Oloogbe Dora Akunyili, obinrin naa ṣe pupọ ninu ilọsiwaju oogun ibilẹ lorilẹ-ede yii, o duro ṣinṣin lori òdodo.

 

Bi mo ṣe bori ogun ipenija ati tawọn alayederu oogun

Ọmọ mẹta lo maa n rin papọ, akọbi ọmọ ni Ogo, ikeji ni Ilara, ikẹta ni Ogun. Ọmọ to ba ti logo, o ti kọ lẹta si ilara, wọn aa bẹrẹ si i ṣe ilara rẹ, ilara yẹn lo maa wa bi ogun. Ẹni t’Ọlọrun ba ti de lade ogo laye yii, o maa niṣoro gan-an o, ṣugbọn o maa bori iṣoro yẹn labẹẹ bo ti wu ko ri.

Ẹlomi-in waye waa najaa warawara ni. Baba mi fi ye mi nigba aye ẹ, pe odo to ba n sun wẹrẹwẹrẹ ki i da, o ni iyẹn ni wọn n pe ni orisun omi.  O ni odo to ba ti n ṣe waa, waa, waa, to ba ti le da wai, o ni ko ni i sun mọ, baba mi lo sọ bẹẹ fun mi. Bi mo dẹ ṣe lo igbesi aye mi niyẹn.

Ṣe ẹ mọ pe mo sọ pe mo ba awọn kan lori atẹgun, mo waa ro o pe bawo ni mo ṣe fẹẹ ṣe eto temi to maa yatọ si tawọn to ti wa lori atẹgun yẹn, mo waa gbe e gba ọna mi-in to yatọ patapata si tiwọn.

Gbogbo ohun ti mo fi n sọrọ lorii tẹlifṣan patapata nigba yẹn ko ju iṣẹju marun-un lọ, nitori ere sinima yẹn ni mo fi n mu awọn eeyan mọra, ti wọn ba ti waa wo o tan, ma a waa sọrọ fun iṣẹju marun-un, o jẹ bii idan ni.

Gbogbo igba yẹn, ilara wa, ogun wa, ṣugbọn wọn o ri nnkan kan ṣe si i. Iran temi lo n ṣoogun, mo jogun ba a ni, ki i ṣe ti pe iṣẹ wo ni mo le ṣe lo gbe mi debẹ.

Baba to bi baba mi, ọdẹ ni, ẹkùn lo maa n di. Baba to bi baba mi ni wọn n pe ni ‘Ori-mẹkun-luyi-abiru gilọgilọ, kẹrun-sike ruru-ruru, Orimẹkun alọtan k’oloun si ke.’’ Ọdẹ ni, o maa n di ẹkun pa ẹran ni, ki i fibọn pa ẹran. Aa di ẹkun, to ba di alẹ, aa wọnu igbo aa pa ẹran jọ, aa tun deeyan pada.

Aa ko awọn iyawo jọ, iyawo mẹjọ lo ni, aa wa ko wọn jọ pẹlu awọn ọmọ, aa ni ki wọn maa lọ ko ẹran wa loko wa sile.

 Ọmọ to bi pọ gan-an, ṣugbọn baba mi nikan lo yaṣẹ iṣegun fun, baba mi nikan naa lo dẹ kilọ fun pe ko gbọdọ wọnu oko lọọ ba wọn du obi tabi koko.

O ni baba mi ko gbọdọ ba wọn du oko kankan boya oko iṣu abi nnkan kan. O ni lọjọ to ti ba ti wọnu igbo lọọ ba wọn du oko, o lo maa ṣi rin, o niṣe òògùn ni ko maa lọọ ṣe.

Ko wa sibi kan ti awọn ọba alaye ko ti ki n waa ṣoogun lọdọ baba mi. Awọn ọba alaye to n wa sọdọ wọn waa ṣoogun ti mo mọ, mọkanla ni wọn.

Ọba Adeyinka Oyekan, ọrẹ baba mi ni to fi ku. Sir Adesọji Aderẹmi, ọrẹ baba mi ni. Fun idi eyi, idile temi ti wa, ibi ti wọn ti n ṣoogun ni, wọn bi i mọ mi ni, ta a ti n ṣe iṣegun ibilẹ ninu idile mi, o ti le lẹẹdẹgbẹta ọdun (500 years).

Ṣugbọn ṣe ẹ mọ pe aye ti di aye irọ nisinyi, tẹ ẹ ba wo gbogbo asiko Alaafia tayọ ta a n sọ yii, ilu ṣi daa, boya nnkan ti ko jẹ kawọn ayederu pọ nigba yẹn ni pe ko ti i si aye packaging, to o ba de ọdọ mi, oo le ri oogun mi. Ki i ṣe nnkan to o kan le lọ sorii  igba ko o ra a.

Ṣugbọn nigba ti iṣẹ iṣegun ti di pe ka maa ṣe packaging, teeyan le ri i ra lori atẹ, ibẹ ni ọrọ ayederu ti wọle. Pe a dẹ waa gbe e debi to daa, ta a ṣe packaging yii ki i ṣe nnkan to buru, awọn eeyan wa ni wọn sọ ọ di bami-in mọ wa lọwọ .

Igba ti mo gbe Ọṣọmọ jade, ko si bita (bitter) kankan ju Alomo ti wọn ko wa lati Ghana lọ. Ọṣọmọ yii nikan lawọn eeyan mọ loogun ibilẹ to n ṣiṣẹẹ bita nigba yẹn, ko ju oṣu mẹta ti mo gbe e jade ti wọn ti ṣe ayederu ẹ mọ mi lọwọ. 

A tun fọlọpaa mu wọn, mo paarọ ike ẹ ati paali, mo waa ṣe e ni tuntun mi-in patapata. A wa ni kootu lọwọ, awọn mẹjọ ni wọn ṣe ayederu yẹn ti mo gbe lọ si kootu, kootu la wa ti wọn lọọ ju ina sileeṣẹ ta a ti n ṣe Ọṣọmọ naa, owo ti mo padanu ju idaji biliọnu kan lọ. ( Over 500Million) lọjọ kan ṣoṣo.

Ṣe ẹyin naa ri i, iru awujọ ta a wa niyẹn, ṣugbọn gbogbo ẹ naa kọ ni ijọba, awa arawa la n ṣera wa. Loootọ, ijọba naa ni ipa tiwọn lati ko, ṣugbọn awọn to n ta ọja yii gan-an naa ni awọn ẹbi tiwọn ti wọn jẹ.

Iwọ to o mọ pe ọja ti wọn gbe wa fun ẹ yii, ayederu ni, ki lo de to o gba lọwọ wọn. Iṣoro Naijiria yii, ọja tabi iṣẹ yowu teeyan ba n ṣe, t’Ọlọrun ni kaye tẹwọ gba a, teeyan ko ba mura, ko too ri ẹgbẹrun mẹrinla lori ẹ, aa rẹni to maa ba a du u nigba ti yoo ba fi di ọjọ keji to bẹrẹ ọja naa, iṣoro ta a ni niyẹn.

 

Tẹ ẹ ba ti ri nnkan tawọn eeyan o ‘kọṕi’ (copy), aa jẹ pe nnkan yẹn o daa. Nnkan to ba ti daa, tawọn eeyan n beere, wọn maa kọpi ẹ, afi to ba jẹ pe owo nla ni wọn fi n bẹrẹ ẹ lo ku.

Simẹnti Dangote, ti wọn ba rọna ati ṣe ayederu ẹ wọn aa ṣe e, o kan jẹ pe wọn ti ri i pe owo kekere ko bẹrẹ ẹ ni, owo ti wọn maa fi ṣe e lagbara diẹ.

Ṣugbọn ninu nnkan to rọrun lati ṣe ayederu ẹ ju ni nnkan mimu, Nigerian Brewery tẹ ẹ ri yẹn, ọja wọn, wọn aa ṣe ayederu ẹ ninu yara olojule meji pere, ṣebi nnkan mimu ni, igba meloo ni wọn maa fi lọọ ra igo Star lọja, wọn aa ko o jọ, wọn aa dẹ bẹrẹ si i rọ ọ, wọn aa dẹ mu ọpa kan, wọn aa fa a wọle.

Tẹ ẹ ba d’ọja nisinyi, ‘bitters’ to wa lọja aa le lẹgbẹrun kan, oriṣiiriṣii.

Bẹẹ ni 2013, tẹ ẹ ba de ori igba, Bitters to wa lọja o le ju marun-un lọ, ṣugbọn eyi to lewaju wọn ni Ọṣọmọ, ikeji, boya Alomọ.

Ẹyin ẹ lọ sọja lonii, wọn ti ju ẹgbẹrun kan lọ, NAFDAC to wa lara ẹ, ayederu nọmba ni. Ibi ti wọn ti n ṣe e, ẹ o le mọ ọn, irọkurọ ni wọn rọ sibẹ.

 

Nigba ti mo gbe Ọṣọmọ jade, awọn oṣiṣẹ mi gbe Ọṣọmọ meji sorii tabili, wọn ni ki n mu ojulowo jade ati ayederu, mo wo o titi, mo ni iṣẹ temi leleyii, mo tun mu ikeji, mo wo o titi, mi o ri iyatọ.

Wọn ni ki n tu u wo, mo tu u,mi o ri nnkan kan. Ni wọn ba ni o daa, ki n jẹ kawọn ja a sinuu kọọbu, wọn ja ìkíní, wọn da a sinuu kọọbu, mo ni temi leleyii. Wọn mu ikeji, wọn da a bayii, oorun gbalẹ, niṣẹ lo dudu kira. Wọn wa ni ayederu yẹn gan-an lo pọ lọja.

Fun idi eyi, ijọba atawọn ileeṣẹ to n ri si ọrọ bi eyi ni ọpọ iṣẹ lati ṣe. Ohun to ba ti le mu ẹ gẹgẹ bii ẹni to n ṣe oogun, to n gbe e lọ sọja, gbogbo iru awọn nnkan bawọnyi ni keeyan ti mọ pe yoo ṣẹlẹ, nitori ko le ṣe ko ma ṣẹlẹ.

 

Akọkọ na, ọja yoowu to ba ti wa ni gbangba ọja, ti Ọlọrun dẹ ni kọja naa bọ si atẹwọgba, ti wọn fẹran ẹ, to ba ti di pe wọn n beere fun un gan-an, ẹni to n ta a gangan lo maa lọọ so mọ ọmọ Ibo kan pe, ‘’Obinna, wọn ti n beere ọja yii pupọ o, o jọ pe ẹni to n ṣe e ko lagbara ẹ mọ, ṣe iwọ le ṣe e?

Ṣe ẹ mọ pe bọja ba ṣe n ta si leeyan yoo ṣe maa pese ẹ si, ti ẹni to ni ọja ko ba ni to ohun tawọn eeyan fẹẹ ra, wahala ti wa, o ti faaye silẹ fun ayederu. Lo ba maa di pe Obinna aa ni ko ma wọri, to ba dọla, oun yoo ba a ko ẹgbẹrun lọna igba ọja naa wa, iṣẹ yẹn ti wọn ṣaago niyẹn.

 

Fun idi eyi, ṣe ijọba ni yẹn abi awarawa?  awa la n para wa, awa funra wa la maa ba ara wa sọrọ.

Tẹ ẹ ba wo awọn bitters to wa lọja ta a n sọ yii, o ti pa ọpọlọpọ eeyan, nitori ọpọlọpọ wọn lo jẹ pe arufin lawọn ti wọn ṣe e, kẹmika buruku ni wọn rọ sinu ẹ.

Wọn aa ni omi-in, to o ba ti mu un bayii, laarin iṣẹju kan, nnkan ọmọkunrin ẹ maa le ni, kẹmika ni, egboogi oloro ni, o dẹ n pa ọpọlọpọ awọn eeyan wa yii, awọn ibi to yẹ kijọba mojuto niyẹn.

Iṣoro to lagbara ni o, yatọ sawọn bitters, tẹ ẹ ba de ọja loniil, ọpọlọpọ nnkan tawọn eeyan n ra lọja ni ko ṣe ara loore, iyẹn lo jẹ ki oriṣiiriṣii aisan pọ niluu. Oun lo jẹ ki itọ ṣuga pọ niluu bii baba eṣua, nitori ayederu ti pọju.

Packaging ayederu nigba mi-in, o maa n daa ju ti ọrijina lọ. Wọn aa pọn ayederu le debii pe ti wọn ba gbe wọn sẹgbẹẹ ara wọn, eeyan aa maa pe ojulowo ni feeki ni.

 

Kekere ni mo ti bẹrẹ iṣẹ iṣegun yii, ṣugbọn mi o le fipa fi le ọmọ lọwọ o

 

  Ọmọ kekere jojolo ni mo wa ti mo ti n ba baba mi lọ oogun lori ọlọ. Nigba ti mo wa lọmọ ọdun mẹfa, baba mi aa gbe ọlọ fun mi, aa ni ki n lọ nnkan lori ẹ.

Awọn kọstọma ẹ ti wọn ba de ti wọn ri mi, wọn aa ni baba, ọmọ yii ṣi kere ! Baba mi aa maa da wọn lohun pe ṣe ti wọn ba fun mi lounjẹ, ṣe idi ni mo maa n fi si abi ẹnu. Ma a ni ẹnu ni, aa ni, ‘’gba a, maa lọọ lọ ọ, nigba to o ti mọ pe ẹnu lounjẹ n lọ.’’

Ṣe ẹ mọ, nnkan ti wọn jẹ bi mi ni. Lati inu iṣẹmi mi wa ni mo ti mọ pe nnkan ti mo fẹẹ ṣe ree. Fun apẹẹrẹ, emi o mọ, ṣugbọn wọn jẹ ki n mọ itan yẹn. Nigba ti mo wa ni kekere, baba mi ṣe oogun, wọn dẹ maa n n lọọ ta ayo nirọlẹ. Wọn waa ṣe oogun kan, wọn rọ ọ sinuu ṣẹẹrẹ, n’Ibadan ni, wọn waa lọọ ta ayo.

Ki baba mi too de, awọn ọmọ adugbo ta a jọ n ṣere ni kekere, mo ba ko wọn wọle, mo waa lọọ gbe oogun yẹn ( Oju mi ni baba mi ṣe ṣe e), mo waa n bu oogun yẹn fun wọn pe ki wọn maa da a jẹ, ki wọn maa lo o.

Oogun yẹn dẹ ree, wọn jo o ni. Ṣe ẹ mọ ọmọ keekeeke, ẹlomi-in da a soju ninu wọn.

 Baba ta a jọ n gbele lo wa de, lo waa ni ki leleyii, bi baba yẹn ṣe sare lọ sibi ti baba mi ti n ta ayo niyẹn, lo ni wo o, ọmọ ẹ ti pa awọn eeyan jọ sinuu  ile.

 Bi baba mi ṣe n sa bọ niyẹn, lo ba ba awọn ọmọ keekeeke loootọ, o ni ki leleyii. Ka ni oogun buruku loogun yii, bo o ṣe maa pa gbogbo wọn niyẹn.

Baba mi jẹ ki n mọ pe oogun ika, beeyan ko ba fi ṣe ara ẹ, aa fi ṣe ọmọ eeyan mi-in. Latigba yẹn, ti baba mi ba ti ṣe oogun, aa ṣe e sinuu ṣẹẹrẹ, aa waa to owo ẹyọ si i, aa fi nnkan pa a lara, aa fi ẹjẹ pa a lara, aa waa di ẹ̀rù, to jẹ ti mo ba ti n ri i bayii, ẹru aa maa ba mi ati sunmọ ọn ni.  

Nigba ti mo wa dagba, mo wa beere lọwọ baba mi pe ki nitumọ awọn owo ẹyọ tẹ ẹ maa n so mọ ara ṣẹẹrẹ oogun yii, o ni emi ni mo fa a, pe ọjọ kan ṣoṣo ni mi o ba pa ọmọ mọkanla, o wa sọ itan yẹn fun mi.

O ni ki i ṣe gbogbo ohun ti wọn to mọ ara kinni yii lo maa jẹ koogun ṣiṣẹ, ṣugbọn lati jẹ kọmọde sa, pe tọmọde ba debi ẹru, ẹru aa ba a, ohun ni gbogbo owo eyọ ti wọn de mọ ọn lara, ati ẹjẹ ti wọn fi pa a lara, ki i ṣe iyẹn lo maa moogun jẹ rara.

 

Awọn oyinbo naa ni ọgbọn tiwọn, bi wọn o ba fẹ kọmọde lo oogun kan, wọn aa ṣe ideri ẹ lọna to jẹ pe tọmọde ba loun fẹẹ ṣi i, o le wa lori ẹ fun wakati mẹwaa, ko ni i ri i ṣi.

Ọmọ to wa jẹ pe lati ọmọ ọdun mẹfa lo ti n ba baba ẹ lọ oogun, o da bii ọmọ to n ba baba ẹ lọ soko naa ni, ṣe ẹ mọ pe to ba ya, o maa wu u lati ṣiṣẹ yẹn. Ohun to maa n fun mi layọ nigba ti baba mi ṣi wa laye ni pe ko si ojumọ naa laye yii ti baba mi o ni gba ẹbun.

 Baba mi o fowo ra aṣọ ẹ ri, awọn kọstọma maa  n gbe aṣọ wa fun un ni. Gbogbo awọn ti wọn wa ni Gbagi, oriṣiiriṣii awọn eeyan bẹẹ yẹn, awọn adajọ, fawọn nnkan oriṣiiriṣii to ti ṣe. Eyi fun mi lọpọ iwuri lati mọ pe mo maa ṣiṣẹ yii.

Ṣugbọn ida aadọrun-un aẁọn oogun ti mo gbe jade nileeṣẹ YEMKEM lonii, awọn oogun ti mo funra mi jade lọọ wadii lori ẹ ni. Nitori abala aye ni iṣẹ ti baba mi ṣe ni tiwọn, iyẹn o dẹ ṣee gbe sori atẹ, mo ni lati jade. Ọpọlọpọ awọn ọrẹ baba mi, ma a lọ sọdọ wọn lati kẹkọọ, mo rin kaakiri lati kẹkọọ si i.

Iṣegun ibilẹ tẹ ẹ ri yẹn, imọ kan ni, teeyan gbọdọ kọ lati iran kan si ikeji.

Ṣe ẹ ri nipa ti ọmọ pe boya wọn aa jogun ẹ, ọmọ to o ba nifẹẹ si pe ko maa ṣiṣẹ ẹ, nigba mi-in, imisi lati ọrun ko ni i fi si i lara.

 Baba mi ko fi bẹẹ ba baba ẹ rin, to ba n lọ si igbo awo, ki i mu baba mi lọ. Iyawo mẹjọ lo ni, ṣugbọn o ni aayo kan ninu wọn, ọmọ tiyawo naa bi to jẹ akọbi tiẹ ni baba mi fẹran ju.

To ba fẹẹ rin irinajo, ọmọ naa torukọ ẹ n jẹ Kelaani lo maa n mu dani, wọn le lọ fun bii oṣu mẹfa nigba mi-in ti wọn o ni i  wa sile. Aburo ni Kelaani ti mo n sọ yii jẹ si baba mi o, ṣugbọn iya ọtọ lo bi i, iya ẹ ni baba-baba mi fẹran ju ninu awọn iyawo mẹjọ to ni. Kelaani yẹn gan-an lo yẹ ko maa ṣiṣẹ yii, ki i ṣe baba mi rara. Kelaani yẹn lo mọ itan baba to bi baba mi, oun lo pa a fun mi ju, baba mi gan-an ko fi bẹẹ sọ ọ fun mi.

 Kelaani lo jẹ ki n mọ pe tawọn ba n lọ ninu igbo, ti alẹ ba ti lẹ, o ni alujọọnu ni baba awọn. O loun maa n ru apẹrẹ oogun baba awọn, o ni baba aa waa pe oun pe ‘Kelaani, gbe ori rẹ wa sibi, aa waa bu oogun sori oun, aa pe ayajọ si i, aa gbe apẹrẹ yẹn le oun lori, aa ni koun maa niṣoo, oṣu mẹfa bẹẹ, wọn o ni i wale.

O ni to ba di alẹ, aa gba apẹrẹ yẹn lori oun, aa gbe e sọwọ, aa ni, ‘Oriṣa oke, gba ẹru ẹ dani soke’. Apẹẹrẹ yẹn maa duro soju ofurufu, ki ojo aye ati tọrun maa rọ, ko ni i debẹ.

O ni inu igbo yẹn ni baba oun maa ti lọọ ge ewe ọgẹdẹ, aa tẹ ẹ silẹ ninu igbo, aa ni koun sun sibẹ. O ni ki iwin ati ẹbọra maa ja, wọn o ni i debi toun ba wa o. O ni baba oun aa rin lọ, oun o ni i ri i, to ba ku diẹ kilẹ mọ, aa ji oun pẹẹ, oun aa tun dide. O ni baba yoo nawọ soke, aa ni Oriṣa Oke, ẹru oun da, ba mi gbe e, aa tun jabọ si i lọwọ, aa tun gbe e le oun lori.

 

Nigba ti baba-baba mi yẹn maa ku, ọjọ meje lo fi n pọ oogun. Ibi ti mo wa n lọ gan-an ree, ṣe ẹ mọ pe Kelaani gan-an lo yẹ ko maa ṣiṣẹ iṣegun lẹyin ikuu baba rẹ, ṣugbọn wọn ni nigba ti baba awọn fẹẹ ya iṣẹ, iyẹn ni mo ṣe sọ pe iṣẹ yii, nnkan atọrunwa ni. O bimọ ọkunrin to pọ loootọ, wọn lo gbe igba kan sinuu yara, o wa n pe awọn ọmọ rẹ yẹn lẹyọ kọọkan. Aa ni lagbaja, lọọ wo inu yara yẹn, nnkan to o ba ti ri ninu igba ko o waa sọ fun mi.

Ti eyi ba wọbẹ, aa jade, aa loun o ri nnkan kan, baba aa ni ko maa lọ, aa tun pe ẹnikeji, iyẹn naa aa tun loun o ri nnkan kan, baba aa tun ni ko maa lọ.

Nigba to kan Kelaani, o ni ko lọọ wo o to ẹẹmẹrin, bẹẹ awọn to ku yẹn, ẹẹkan pere to ba ti ni ki wọn lọọ wo o, ti wọn ba ti lawọn o ri nnkan kan, aa ni ki wọn maa lọ ni. Ṣugbọn nitori ifẹ to ni si Kelaani ati iya ẹ, o ni ko lọọ wo o lẹẹmẹrin, iyẹn o ri nnkan kan.

Lo wa kan dadi mi, Dada dẹ ni baba mi. O ni ki baba mi lọọ wo o, ni baba mi ba jade, lo ba ni baba, mo ri nnkan. Mo ri aafin, mo ri ọba kan to gbe ade sori, baba tun ni ko lọ sibẹ ko lọọ wo o, ẹẹmẹta ni baba mi wọ yara yẹn to n sọ nnkan toun ri ninu igba fun baba rẹ.

Ibi to ti waa fa baba mi mọra niyẹn, to ni ẹni toun maa fiṣẹ le lọwọ ree. Ṣe ẹ ri i bẹẹ yẹn, iṣẹ yii ki i ṣe nnkan teeyan kan n sare wọnu ẹ, o ju bẹẹ lọ.

Mo ni ọmọkunrin kan nisinyi, ẹkọ nipa oogun ibilẹ lo kọ ni England. Emi kọ ni mo ni ko lọọ kọ ọ, funra ẹ lo ni ohun toun fẹẹ ṣe niyẹn. O ti kọ nipa pipo oogun atawọn mi-in, funra ẹ lo ni oun nifẹẹ siṣẹ yii.

  Ṣe ẹ mọ pe nnkan to ba wu eeyan latọkan, o yatọ si nnkan ti wọn fipa muuyan lati lọọ ṣe. Ohun lo maa n fa a to jẹ pe ọpọlọpọ eeyan lo ti sa wọnu iṣẹ iṣegun yii, nitori wọn gbagbọ pe iṣẹ yii ni YEMKEM ṣe to fi lowo, jẹ k’emi naa sa wọnu ẹ. Ọpọlọpọ lo ti sa wọnu iṣẹ yii ti wọn ti pada sa jade.

Tẹ ẹ ba wo awọn ta a ba niwaju, awọn kan ti wa lori atẹgun to jẹ aye mọ wọn kawa too bẹrẹ eto lorii tẹlifiṣan, ti wọn o gburoo wọn mọ lonii yii.

Awọn kan n ṣiṣẹ yii niṣee pe kọmọ de ba a nilẹ, ki wọn jogun ẹ, awọn kan si n ṣe e niṣee pe ki wọn ri owo ki wọn dẹ ya danu kuro nibẹ ni, awọn iyẹn ni wọn pọ ju.

Awọn mi-in ti fi lu jibiti, wọn ti ya danu, ẹjọ wọn si kọ, ipo ti wọn ba a ni. Ṣugbọn to ba je pe ko ti i sẹni kan to ṣiṣẹ yii laṣela nilẹẹ Yoruba, ko sẹni to maa ya sibẹ, wọn aa maa sa kuro nibẹ ni. Wọn ti ri i pe iṣẹ aṣela ni, ṣugbọn iṣẹ aṣela yẹn, ṣe awọn to ṣe e laṣela footọ inu ṣe e ni wọn fi ri i ṣe ni, abi iwọ fẹẹ ṣe e niṣee pe ko o lu jibiti nidii ẹ ko maa lọ?

 

   Lasiko Korona, mo ṣe oogun to le kapa ẹ,ijọba ni ko tete fọwọ si i

Ni 2020, mi o ni i gbagbe laye mi, mo wa nile mi ni Kabiyesi Ọọni Ifẹ, Ẹniitan Ọjaja ba pe mi, wọn ni ki ni mo fẹẹ maa wo, wọn lo yẹ ki n ti gbe oogun ẹ jade.

Mo ni Kabiyesi, bẹẹ ni, ibi ta a ti bẹrẹ niyẹn.

Awọn egbo ti kabiyesi naa ni, wọn fi ranṣẹ si mi lori ayelujara, eyi temi naa ni, mo gbe e kalẹ, a to gbogbo ẹ papọ, ohun la fi gbe oogun kan jade ta a pe ni Feroxil.

Ṣe ẹ mọ pe ọrọ NAFDAC o ki n ya, wọn dẹ ni oogun tawọn o ba fọwọ si, ao le gbe e jade. Ki n too le ri oogun yẹn gbe jade, o ti n lọ si bii 2021, a gba aṣẹ ẹ ni 2022 la fi gbe e jade nigba yẹn, a ṣe e lolomi, a ṣe e ni kapsu.

Ewuro ni Ọọni sọ pe ki n ṣiṣẹ le lori nigba yẹn, wọn ni ki n ṣe e ni kapsu ki n gbe e jade, bi Kabiyesi tun ṣe gbowo kalẹ niyẹn, a dẹ gbe e jade.

 Oogun yẹn nigba yẹn, gbogbo awọn eeyan ti Kabiyesi fun titi de ileeṣẹ Aarẹ, wọn lo o, nitori bo ṣe n pa arun lo tun dena aarun. O maa n fun awọn ṣọja ara wa lagbara ni.

 Ṣe ẹ ri gbogbo abẹrẹ ajẹsara yẹn, atọwọda iro-ara-lagbara lo n fun wọn. Eyi to jẹ tewe-tegbo lo daa ju lati tun ara ṣe lọna Iṣẹda, ti ko ni wahala ninu.

Nitori kokoro Korona maa n pa awọn ṣọja ara ni, to ba ti pa wọn tan, aaye aa wa fawọn aisan lati wọnu ara, oogun yẹn la gbe jade lati tun ṣọja ara ṣe, ko si dena ara kuro lọwọ ikọlu awọn kokoro aifojuri.

 Ṣugbọn ilu ta a wa yii, nnkan ibilẹ tiwa ki i jọ wa loju. Ni gbogbo igba yẹn, ẹ o ri i pe ilu oyinbo nikan nijọba ti n ko oogun wa. Gbogbo igbesẹ ti awa n ṣe lati jẹ koogun yii wa kiri ki wọn maa lo o, ko seso rere.

Afi nigba ti Aarẹ Madagascar ṣẹṣẹ jade, ti aarẹ orilẹ ede kekere naa ṣafihan oogun tiwọn, to wa n lo o, nigba yẹn lawa naa ṣẹṣẹ wa n sọ pe oogun ibilẹ ni wọn n lo, awa naa ni eyi to ju bẹẹ lọ.

O ṣe maa jẹ ilu kekere bẹẹ yẹn lo maa lo nnkan ti awa ṣẹṣẹ waa maa maa forikori, ki lo de?

 

Bi ẹka iṣẹ tiata  ṣe dà lasiko yii ni mi o ṣe polowo ọja nibẹ mọ

 

Nnkan to ṣẹlẹ ni pe mo n gbe awọn oṣere jade nigba yẹn, emi ni mo n kowo sẹka awọn onitiata ju nigba yẹn, mo dẹ maa n lo awọn fiimu wọn lati gbe awọn ọja mi larugẹ.

Ṣugbọn lasiko yii, adinku ti de ba bi wọn  ṣe n ṣe fiimu. Ati pe ọpọn tiwa naa ti sun siwaju, ọja wa nikan la gbajumọ bayii.

Igba yẹn dẹ tun ree, awọn iṣẹ to jẹ mọ ti aye la n ṣe, ṣugbọn nisinyi, iṣẹ ka pese oogun yii ni mo n ṣe ju.

Yatọ siyẹn, a o kowo le tiata mọ, nitori nigba yẹn, ko si fiimu too maa ya, to o ba gbe e jade, ọjọ to ba jade, o kere ju, wa a ta ẹẹdẹgbẹta (50,000 copies).

Ṣugbọn nisinyin too ba ṣe fiimu sita to o gbe e jade, boya lo fi le ri awọn eeyan to maa ra a. Ohun to n ṣẹlẹ bayii ti ko ba ẹka fiimu ṣiṣe.

 

Mo fẹẹ fi ọjọọbi ọgọta ọdun mi yii dupẹ ni, ki i ṣe talariwo

Mo dupẹ pe mi o si lori idubulẹ aisan, mo dupẹ ibi ti Oluwa ọba gbe mi de. Mi o foju sunkun aya, mi o foju sunkun  ọmọ. Mo tun waa fẹẹ fiyin f’Ọlọrun nitori gbogbo awọn iji to ti ja, t’Ọlọrun o ni ko bori mi mọlẹ, ọpọlọpọ ipenija ti mo ti ri laye yii, tẹlomi-in ba ri ida kan rẹ, wọn aa gbe e gbin. Mo dupẹ.

Ṣe tawọn oṣiṣẹ ni ka sọ ni. Ọjọ ti ileeṣẹ mi jona, ọjọ keji lawọn oṣiṣẹ tun bẹrẹ si i ja mi lole, wọn dẹ jale owo to le ni miliọnu mẹtalelogun.

Pathfinder Hotel, otẹẹli mi to wa l’Ado, o maa pe ọdun mejidinlogun ti mo ti kọ ọ, ole ni wọn ja nibẹ.

Oṣooṣu ni wọn n ji Disu lita ẹgbẹrun mẹrin. Mo ra mọto tuntun ni Elizade Motors, mo gbe e lọ fun wọn pe ki wọn maa fi ṣe ‘Car hire’, ọjọ kẹta ni wọn ni ole gba a lọwọ wọn.  

Gẹgẹ bi ẹni to n ṣowo to si koju awọn nnkan wọnyi, t’Ọlọrun dẹ jẹ keeyan wa laye, keeyan dupẹ f’Ọlọrun ni, Alhamdulilah, Ọlọrun mo dupẹ .

No comments:

Post a Comment

Adbox