IROYIN YAJOYAJO

ipolowo

Thursday 13 July 2023

Oriire nla ni Tinubu je fun Iran Yoruba, e je ka gbaruku ti i-Oloye Moshood Salvador





Teeyan ba ni eegun baba oun yoo jo, to ba tun ya to ni eegun ọhun ko ni i jo mọ, ko sẹni kan ti yoo muuyan si i. Eeyan ko baa si ti maa ṣe oṣelu bọ latọdun-un pipẹ, ko to akoko kan ko ni oun ko ri toṣelu ro mọ, kiluu ṣaa ti lọ siwaju loun n fẹ bayii, deede naa ni.

Eyi lakawe to ṣe rẹgi Oloye Moshood Salvador, ọmọ wọn nipinlẹ Eko, ni Popo Aguda (Brazillian Quaters) to ti ṣe Alaga PDP ri l’Ekoo, to ṣe oṣelu laye awọn AD titi to fi pada di APC, Baba ṣe ẹgbẹ Labour paapaa, ṣugbọn ni bayii, Baba Salvador loun ko tiẹ fẹẹ gbọ kinni kan oṣelu mọ, o ni àtẹ̀gùn lasan teeyan fi n jẹ ọmọ ẹgbẹ loṣelu, oṣelu kọ leeyan fi n ri ti orilẹ-ede rẹ ro, oṣelu kọ leeyan fi n ṣe daadaa siluu to n dari.

Oloye Salvador ni keeyan ma pe oun loloṣelu mọ o.

Nile rẹ to wa ni Surulere, niluu Eko ni Salvador ti sọrọ yii lọjọ Iṣẹgun ọsẹ yii fawọn ọmọ ẹgbẹ akọroyin ledee Yoruba, League of Yoruba Media Practitioners (LYMP), ti wọn ṣaa fẹẹ mọ ẹgbẹ ti baba naa wa bayii.

Salvador sọ pe, ’’Ṣebi ẹ ri i pe nigba ti wọn fi Ọbasanjọ ṣe aarẹ Naijiria ninu ẹgbẹ PDP ni 1999, o yan awọn eeyan sipo ni gbogbo ipinlẹ, awa Yoruba lo fiya jẹ. Awọn ara Oke-Ọya ni wọn yan an sipo, awọn ni wọn sọ ohun ti yoo ṣe fun un, ko lagbara. Lasiko yii ti Aarẹ Bọla Tinubu wa nipo ni mo gba pe a ṣẹṣẹ ni aarẹ to jẹ Yoruba, saa tiẹ ni isọri lẹkun-jẹkun (Constituency) wa daadaa. Ẹni to ni agbekalẹ (Structure), to tun ni ‘Constituency’ to si ti n ja ijangbara fun ilẹ Yoruba tẹlẹ ko too di aarẹ, akọkọ ree.

‘’Ẹ fi ẹgbẹ oṣelu silẹ. A ni kẹ ẹ yọ ẹgun to gun yin lẹsẹ, ẹ n tayin, kẹ ẹ too tayin tan, ẹgun aa ti toro siyin lara lọ. A n sọrọ ilọsiwaju ilu, ẹ n sọrọ oṣelu. Bi mo ṣe wa yii, mi o raye oṣelu kankan,mi o jisoro oṣelu. Ninu ida ọgọrun-un asiko mi, ida mẹwaa pere loṣelu ri gba, eyi to ku, mo fi n mojuto iṣẹ mi ni. Mi o gba kọntiraati oṣelu ri latijọ ti mo ti n ba a bọ, awa n fowo tiwa ran oṣẹlu lọwọ ni, ẹ lọọ beere wo.

‘’Ẹ jẹ ka ṣatilẹyin fun Aarẹ tuntun yii, ilọsiwaju ilẹẹ Yoruba lo ṣe pataki bayii, ẹgbẹ oṣelu kọ’’

Lẹyin alaye yii ni Oloye Moshood Salvador dahun ibeere lori aigbọra-ẹni-ye to ti pin ẹgbẹ Afẹnifere si meji, ti Baba Ayọ Adebanjọ ati Baba Rueben Faṣọranti ti di igun meji ọtọọtọ.

Oloye Salvador sọ pe, ‘’o ṣeni laaanu pe ori awọn agba lo n wọ lọja bayii, ti ọmọ tuntun kọ mọ.

A maa mura lati ba ara wa sọ ootọ ọrọ. Ọmọ ẹni ki i ṣedi bẹbẹrẹ ka filẹkẹ si tọmọ ẹlomi-in lo mu Baba Faṣọranti ṣe ohun ti wọn ṣe.

‘’Baba Adebanjọ loun n ba Tinubu ja, afi ti wọn ba ṣe atunto ti i ṣe restructuring nikan loun yoo too jawọ. Atunto naa kọ ni wọn ti to silẹ yii ni. Gbogbo nnkan ta a to kalẹ nigba ta a ṣepade apapọ ni 2014 ni wọn ti n ṣe nijọba tuntun yii bayii.

Adua ni kẹ ẹ maa fi ran Aarẹ tuntun yii lọwọ, nitori bi awọn ara Oke-Ọya ko ba pa a, wọn maa di ero ẹyin patapata bo ṣe n ba a lọ yii. Restucturing lo tun ti gbe siwaju wọn yii.

O ti ṣeto pe ki aparo kan ma ga jukan lọ, ki kaluku ṣiṣẹ owo ipinlẹ rẹ, ipinlẹ ti ko ba le pawo tijọba apapọ n fẹ, wọn maa kede ẹ pe ilu o fararọ nibẹ ni, ki kaluku lo nnkan alumọni rẹ, ki wọn ma jokoo ti owo ijọba apapọ. A ṣẹṣẹ fẹẹ mura ilọsiwaju niyẹn.

‘’Ara ohun ti awọn aarẹ ECOWAS ri niyẹn ti wọn fi ni aarẹ wa ni yoo jẹ olori awọn. Ṣe ẹ mọ pe Aarẹ wa ko mọ pe wọn yoo yan oun sipo naa, ijọniloju lo jẹ fun un, ẹni to jẹ aarẹ ti ko ti i pe oṣu mẹta. Awọn ohun ti awọn aarẹ ECOWAS ri to jọ wọn loju lara rẹ, t’ẹyin ọmọ Yoruba ba ni ẹ o ri i, wahala tiyin niyẹn o’’

Lori awọn eeyan ti wọn n pe Aarẹ Tinubu si akiyesi, pe awọn ọmọ Yoruba to n yan sipo ti pọju, Salvador sọ pe beeyan yoo ba da Tinubu lẹbi lori eyi, ẹbi ọhun gbọdọ mọ niwọn.

O ni ta ni ko mọ pe beeyan ba fun were paapaa lọkọ, ọdọ ara rẹ ni yoo roko si, ka ma ti i waa sọ pe ko tiẹ yẹ keeyan da Aṣiwaju lẹbi rara ni. ‘’Ọrọ lasan ni kẹ ẹ maa sọ fun un, imọran lasan lẹ le maa gba a.’’ Bẹẹ ni Oloye Salvador wi.

Yoruba Nation tawọn kan ṣi n pongbẹ rẹ nkọ lawọn akọroyin tun beere, ti wọn fẹẹ ko waye dandan. Ọkunrin to loun ko ṣoṣelu mọ yii sọ pe gbogbo ohun ta a ba n ṣe, ka maa fi ọpọlọ ṣe e lo daa.

O ni awọn kan ko nnkan ogun dani, awọn kan ko ni nnkan kan lọwọ, wọn si n pariwo Yoruba Nation. O ni ki i ṣe pe Yoruba Nation ko daa, ko si ki i ṣe pe oun ko faramọ ọn, ṣugbọn kawọn Yoruba fi laakaye ṣe e.

Eyi ta a gbe dani yii, Salvador sọ pe ao ti i mọ ibi ta a n lọ lori rẹ. Ariwo kọ ni yoo mu Yoruba Nation waye, yoo wulẹ jẹ kawọn eeyan padanu ẹmi ni.

Baba Salvador ko ṣai mẹnuba bo ṣe jẹ nnkan pataki to lati yanju awọn eeyan ti wọn fẹẹ da omi alaafia ilu yii ru, awọn ti wọn n ti awọn agbesunmọmi ta a mọ si bandiiti lẹyin.

O ni iku lo yẹ fawọn ti wọn n pe fun idunaa-dura pẹlu awọn ajinigbe to n pa Naijiria lẹkun, nitori a ki i ba ole to fẹẹ jaayan dunaa-dura pe ko waa ja ile ẹni, eeyan maa n kapa wọn ni.

Bakan naa lo gba awọn eeyan Naijiria nimọran, pe dandan ni iṣẹ agbẹ yẹ ko jẹ fun ẹnikọọkan wọn.

Salvador sọ pe oun ki i fowo ra ohun jijẹ ni toun, o ni inu ọgba toun gbin gbogbo nnkan jijẹ si loun ti mu ohun toun ba fẹẹ jẹ.

Titi kan nnkan ọsin lo ni oun n sin paapaa, oun ki i fowo ra ẹran. O ni bi ẹni kọọkan ọmọ Naijiria naa ba le lo aaye ti wọn ba ni lati ṣe ọgbin, ti wọn n gbin ata, gbin ewebẹ, gbin eso ti wọn tun n sin ẹranko ile, ẹya kan ko ni i t’okere waa maa fọwọ lalẹ fun ikeji rẹ, ohun ti kaluku ba n ṣe ni yoo maa jẹ.

O ni ohun to le mu idagbasoke wa naa ree, bi a ba ṣetan lati tẹle e.

Bi ẹnikẹni ba si n ko wa ni biliọnu sapo ara ẹ, Salvador ni ki wọn ṣofin iya nla fun wọn ni (Capital punishment).

Eyi wa lati kapa iwa ajẹbanu awọn oloṣelu gẹgẹ bo ṣe wi, bijọba yii ba n yọ awọn kan kuro to n fi awọn mi-in si i lai ṣe ofin to le ka awọn ole nla yii lapa ko, Salvador sọ pe bi ẹni to n pọnmi sinu apẹrẹ ni.

No comments:

Post a Comment

Adbox