IROYIN YAJOYAJO

ipolowo

Monday 18 October 2021

Éyi ni bi 'Conscience Forum' se dibo yan Mustapha Dabiri gege bi alaga egbe oselu APC ipinle Eko


 
Lati le ma je ki awon alagbara ninu egbe APC nipinle Eko, fowo agbara gba won, lori bi won se gba foomu lati dije fun ti awon ipo oloye egbe sugbon ti won ko je ki won se ojuse won bi omo egbe naa. Conscience Forum naa seto ibo ti won naa laye oto.
 
Lojo Abameta, Satide, ose to koja yii ni Conscience Forum, eyi ti Onarebu Moshood je adari won dibo yan Mustapha Dabiri atawon marundinlogoji mii in gege bi oloye fegbe oselu APC, ipinle Eko.
 
Nibi ibo naa to waye ni Irewole Event Centre, niluu Eko, lawon omo egbe naa ti dibo yan awcn oloye tuntun ohun.
 Awon yooku ti won tun dibo yan ni Alhaji Akeem Fagbemi (Mushin) gege bi igbakeji alaga nigba ti Onarebu Olujimi Shobayo  lati Amuwo-Odofin je igbakeji akowe.
 
Awon yooku ti won tun dibo yan ni Olukogbon Stephen Babatunde (Ikeja), toun je igbakeji akowe, Eni-owo Adesegun Samson, igbakeji alaga,Onarebu Kunle Okunola (Ikeja), igbakeji alaga loun naa.
 
Bee naa ni  Onarebu Adebowale Adeshakin (Surulere), naa tun je igbakeji alaga, Amofin  Ibijoke Tijani Fadugba (Ifako Ijaiye), ni oludamoran won nipa ofin,  nigba ti AmofinTunde Adelekan Ajibade, si je igbakeji e. Arabinrin Modupe Awe (Alimosho), ni Akapo
Nigba to n soro nibi eto ibo naa, Onarebu Salvador, to je alaga iko naa gba awon olori egbe lamoran lati ma se gba igbakugba laaye.
 
 
O ni ki won ma se nnkan to le mu wahala ba ibo ojo iwaju, nitori bi nnkan se n loo yii, idaamu nla ni yoo muu wa ti agbara si le ma ka mo.
 
Okan lara awon omo egbe toun naa tun soro lojo naa so pe inu awon ko dun si nnkan to n waye ninu egbe oselu APC, nitori bo se je pe orisirisi igun lo se ibo lodo won ti ko si ye ko ri bee.
 
O ni ohun to dara ni bi awon oloye egbe lapapo ba le tete gbe igbese, ki nnkan ko ma ba a baje ju bayii lo. Bakan naa ni iru ibo mii in to tun waye ni egbe naa ni won ti yan
Pasito Cornelius Ojelabi, gege bi alaga fun ti iko mainstream Lagos APC, nigba tawon ti Lagos4Lagos Movement yan Prince Sunday Ajayi, bi alaga todo ti won,Beatrice Omotayo lawon ti Akinwunmi Ambode-led AAMCO  naa yan lodo ti won.
 Ni bayii alaga egbe oselu APC ipinle Eko, ti di merin, ta a wa ni eru n ba bayii.

1 comment:

  1. Thanks for your good report pls kindly 🙏 forward your news to BUNDLION

    ReplyDelete

Adbox