IROYIN YAJOYAJO

ipolowo

Sunday 10 July 2022

Alawada ni Obi ati Kwankwaso, wọn ko le di aarẹ orileede yii-Primate Ayọdele

Olori ijọ ‘INRI Evangelical Church’ to wa ni Oke-Afa, nipinlẹ Eko, Primate Babatunde Elijah Ayọdele ti sọ pe ko si aarẹ laarin awọn oludije ipo aarẹ lorileede yii, iyẹn Rabiu Kwankwaso ati Peter Obi, o ṣapejuwe awọn mejeeji bii alawada adiyẹ. Primate Ayọdele sọrọ yii lasiko to ṣafihan awọn akojọpọ iwe asọtẹlẹ rẹ to pe ‘Warning To The Natioń tọdun 2023 ati siwaju si I lo ti sọrọ yii fun awọn oniroyin lọjọ Abamẹta, Satide to kọja yii .

Woolii arinna  yii sọ pe  Peter Obi ati Kwankwaso n da ara wọn laamu lasan ni, ko si aarẹ ninu wọn, koda alariwo lasan ni Kwankwaso ni tiẹ pa, ko ni i ibi i lọ. Awọn ẹya Igbo lo yẹ ki ọpa aṣẹ aarẹ orileede yii bọ si lọwọ, ṣugbọn wọn ko ni eto rara, eyi yoo si jẹ ki wọn padanu ipo aarẹ titi aye. Ko si ẹni ti yoo gbe orileede yii de ilẹ ileri laarin Atiku, Peter Obi ati Tinubu, atunto nikan ni yoo yanju wahala to n ba orileede yii finra. 

O ni `Mo fẹẹ fi da yin loju pe awọn iṣoro to n ba wa  finra yii yoo tun tẹ siwaju si i, ibo ọdun 2023 ko le mu ayipada kankan wa fun orileede yii. Bi Tinubu ba wọle ibo a jẹ pe o ṣe ojooro ni. Ki i ṣe pe mo korira Tinubu, ohun to wu emi naa ni pe ki ipo aarẹ bọ sọwọ Yoruba. Ti Tinubu ba di aarẹ, ninu ko ma lo asiko rẹ tan nipa a i lera rẹ tabi ki wọn pa a. Ohun ti mo n sọ yii ki i ṣe ọrọ ẹran ara ohun ti Ọlọrun sọ fun mi ni mo n wi.

A ti sọ ọ nigba kan ri i pe wọn yoo kọlu aarẹ, ṣugbọn awọn to wa nile agbara ko gba ọrọ yii gbọ, ṣe ni wọn n bu wa. Mi o korira Buhari, koda o ti wa si ọdọ mi ri nigba ti ile- ijọsin si wa ninu igbo, Jimọh Ibraheem lo mu un wa, ohun ti a sọ fun un nigba naa ni pe yoo di aarẹ, o si ri bi a se sọ ọ.    

No comments:

Post a Comment

Adbox