IROYIN YAJOYAJO

ipolowo

Sunday, 5 June 2022

Àwọn olórin ẹ̀mí yóò dábírà níbi ètò àsírí ààbò àti ìṣẹ́gun tó dájú



Gọngọ yoo sọ lọjọ kejila osu kẹfa, ọdun yii, nibi eto iyin ita gbangba  ti ijọ onigbagbọ kan ti orukọ ẹ n jẹ ‘De Praise Army Of The Lord World Outreach fẹẹ ṣe. Gẹgẹ bi a ṣe gbọ, Abule-Ijoko, nipinlẹ Ogun eto naa yoo ti waye.

Iyin ita gbangba ọhun ti wọn pe akọle rẹ ni  ‘The Shout of Halleluyah’ lorisirisi orin, iyi ati idupẹ yoo ti waye. Diẹ ninu awọn gbajumọ olorin ẹmi ti wọn n reti nibẹ ni:Pasitọ  Ariwo Ayọ,  Ẹfanjẹliisi Wale Peculiar, Purofẹẹti Alayọ Omonije, Ẹfanjẹliisi  Gbemiṣọla Ajigbare ati Ẹfanjẹliisi Aluyọ  Oluwatosin.

Bakan naa lawọn awọn akọrin ijọ  lorisirisi yoo forin yin Ọlọrun logo lọjọ naa.

Ojisẹ Ọlọrun ti yoo fi ọrọ Ọlọrun bọ awọn eeyan ni Pasitọ Fẹmi Lawal tijọ ‘Foursquare Gospel Church’.

Lasiko to n ba wa sọrọ, oludasilẹ  ajọ oniyinrere yii, Pasitọ Olusayọ Olumayọwa Timothy sọ pe ko si ohun meji ti awọn fi gbe iyin ita gbangba yii kalẹ ju pe lati fi dupẹ lọwọ Ọlọrun ati lati fi jeere awọn ọkan tuntun yii ajara rẹ. Ojisẹ Ọlọrun yii to tun jẹ gbajumọ adari fiimu ati onkọtan sọ pe ọjọ kejila, oṣu kejila ọdun 2012 ni iṣẹ iranṣẹ  ti oun pe ni ‘Street Praise’ bẹrẹ, ṣugbọn ṣaaju igba naa ni oun ti bẹrẹ ‘De praise Army of The Lord World Outreach, eyi  to waye lọjọ kejilelogun osu kẹrin ọdun 2012 kan naa.  Mushin, ni Somolu, Abule-Ẹgba, Akute, Ibadan, Akọka  lo lawọn ti gbe eto naa de.

Ojiṣẹ Ọlọrun yii tẹ siwaju ninu ọrọ ẹ pe nigba to ya ni awọn sọ iyin ita gbangba naa di osu mẹtamẹta,  o ni ọjọ majẹmu iyin pẹlu Ọlọrun ni eyi to n bọ lọjọ kejila oṣu kẹfa ti a wa yii yoo jẹ, bẹẹ lo sọ pe pẹlu oore ọfẹ Ọlọrun ọpọ eeyan ni wọn yoo kọrin ayọ kuro nibi iyin ita gbangba naa.   

4 comments:

  1. HALLELUYAH
    HALLELUYAH
    HALLELUYAH
    HALLELUYAH
    HALLELUYAH
    HALLELUYAH
    HALLELUYAH

    ReplyDelete
  2. God will direct your path and glorify His Holy Name.

    ReplyDelete
  3. WAO, glory be to God, the Lord has done it, the Lord will give us a favourable weather in Jesus name

    ReplyDelete

Adbox